Republic of Benin: ìtàn tó bí abẹ́sàn án kọjá bẹ́ẹ̀!

Àkọlé fídíò, Republic of Benin: ìtàn tó bí abẹ́sàn án kọjá bẹ́ẹ̀!

Ogún lé Olori oníkòyí títí to fi rọbi sójúbọ.

BBC Yorùbá ba Oloye Tolulaṣẹ Oguntosin to jẹ Alajaṣẹ ti Ajaṣẹ sọrọ lori ọmọ mẹsan an ti Olorì bi si agbegbe yii to fi sọ ibẹ̀ di ojúbọ oriṣa ni Benin Republic.

Bi ọmọ ko ba itan, o di dandan kó bá àrọ́bá to jẹ baba ìtàn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbegbe Abẹ́sàn án ni orilẹ-ede Republic of Benin ni ìtàn ni pé ikunlẹ abiyamọ ba Olori Oba Onikoyi, Ọba Ganju Ọnọta nigba ti o n sa asala fun ẹmi rẹ lasiko ogun.

Nibẹ lo ti rọbi to bi odindin ọmọ mẹsan an nikunlẹ kan ṣoṣo.

Alajaṣẹ ti Ajaṣẹ ṣalaye fun BBC Yoruba nigba ti wọn n fọrọ waa lẹnuwo ni orilẹ-ede Benin Republic wo pé agbegbe naa ti di ojubọ paraki ninu ilu naa.

Wọn ni obinrin marun un àti ọkunrin mẹrin lanti-lanti ni o bí lọjọ naa ni eyi ti wọn fi sọ agbegbe naa di ojubọ ọmọ mẹsan an ti o pada di abẹ́sàn án.