Ọwọ́ tẹ afurasí méjì tó lá inú aláboyún, tó tún jí ọmọ inú rẹ̀ gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obinrin alaboyun kan ti kú lẹyin ti awọn oniṣẹ ibi meji kan la inú rẹ̀, ti wọn si ji ọmọ inu rẹ gbé.
Awọn alaṣẹ ni Mexico sọ lọjọ Aje pe ọwọ agbofinro tẹ awọn mejeeji, ti wọn si ba ọmọ tuntun naa ni akata wọn.
Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro agba ni ipinlẹ Veracruz ṣe sọ, wọn ri ọmọ naa doola ni alaafia, to si ti n gba itọju.
Awọn afurasi naa, ọkunrin kan ati obinrin kan ni wọn fi ẹsun kan nile ẹjọ pe, wọn fi ọbẹ la inu alaboyun naa, wọn si ji ọmọ rẹ gbe salọ nitori pe obinrin aarin wọn ko ri ọmọ bi.
Awọn ibatan obinrin naa sọ fun awọn akọroyin pe lati ori ayelujara ni wọn ti fi ẹtan mu obinrin naa, pẹlu ileri pe awọn yoo fun ọmọ rẹ ni aṣọ.
Ẹsun ijinigbe ati ipaniyan nitori pe o jẹ obinrin ‘femicide’, ni wọn fi kan awọn afurasi naa.
O le ni ẹgbẹrun mẹta obinrin, ti wọn ṣekupa ni Mexico lọdun 2021.
Ẹgbẹrun kan ninu wọn si ni wọn pa nitori pe wọn jẹ obinrin.
Iṣẹlẹ yii waye lai ti i pe oṣu kan ti ile ẹjọ kan ni Texa da ẹjọ iku fun obinrin kan, fun ẹsun pe o pa obinrin alaboyun kan, to si gbe ọmọ inu rẹ jade.















