Àwọn agbégbọn jí kọmíṣọ́nnà gbé lọ ní Benue wo ibi tí ìwádìí dé dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbebọn kan ti ji kọmiṣọna fun ọrọ ile gbigbe ati idagbasoke awujọ ipinlẹ Benue, Ekpe Ogbu, gbe lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Sewuese Anene lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC.
O sọ pe oun funra oun yoo fi ẹsẹ kan de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye fun iwadii to peye.
Awọn to wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye sọ pe orita Adankari, to wa ni opopona Otukpo si Ado ni wọn ti ji kọmiṣọna naa gbe.
Iroyin ni orita Adankari yii ti ibi ti iṣẹlẹ ijinigbe ti maa n waye lemọlemọ ni bayii ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ti waye nibẹ nigba mẹta ọtọtọ.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ ji alufaa kan gbe nibẹ, to fi mọ Ọjọgbọn kan nile ẹkọ Benue State University, ati oloṣelu kan ni orita yii kan naa.
Bayo ni iṣẹlẹ naa ṣer waye?
Agbẹnusọ ijọba Benue, Terver Akase ṣalaye fun BBC pe ile ijọsin ni kọmiṣọna ọhun ti n bọ ki wọn to ji gbe.
Terver ni kọmiṣọna ọhun, awakọ rẹ ati ẹlomiran to wa pẹlu rẹ ni wọn ji gbe lọ.
Amọ awọn iroyin mii sọ pe asiko ti ọkunrin naa n lọ si abule rẹ lẹyin to kuro ni ṣọọṣi ni wọn ji gbe.
Ta ni Ekpe Ogbu, kọmiṣọna ti wọ ji gbe?

Oríṣun àwòrán, Others
Ekpe Ogbu ni kọmiṣọna fun ọrọ ile gbigbe ati idagbasoke awujọ ni ipinlẹ Benue.
O ti kọkọ ṣiṣẹ gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ Ado, ni ipinlẹ Benue yii kan naa ri.
Ninu eto dibo ọdun 2019, Ekpe Ogbu dije du ipo aṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.












