Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde ẹ̀bùn #2.5 mílíọ̀nù fún ẹni tó bá mọ́ bí wọ́n ṣe lè mú àwọn jàǹdùkú wọ́nyìí

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde láti fún ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀ tàbí nímọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè mú àwọn tó ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ àjọ tó ń ṣètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè yìí, INEC tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ogun ní owó mílíọ̀nù #2.5.
Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni àwọn jàǹdùkú kan lọ ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ INEC tó wà ní Iyana Mortuary ní ìjọba ìbílẹ̀ ẹkùn gúúsù Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn jàǹdùkú náà ló yọ́ wọ ọgbá INEC láàárín òru tí wọ́n sì dáná sun gbogbo iléeṣẹ́ náà.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn jàǹdùkú náà fi epo bẹntiróòlù sínú búrẹ́dì, tí wọ́n sì ju búrẹ́dì náà sí gbogbo iléeṣẹ́ náà káàkiri kí wọ́n tó sọ iná si.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Lanre Bankole ti darí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíákíá láti fojú àwọn tó ṣe ìkọlù náà léde.
Abimbola ní kí ìwádìí náà le wáyé ní kíákíá, Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ti ní ẹnikẹ́ ni tó bá nímọ̀ nípa bí wọ́n ṣe le mú àwọn tó hùwpa láabi náà ni àwọn yóò ní ẹ̀bùn owọ mílíọ̀nù méjì àbọ̀ náírà.
Wọ́n ní wí pé yàtọ́ sí fífún ẹnikẹ́ni tó bá mọ ohunkóhun nípa bí àwọn ṣe lè rí àwọn tó wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú ní owó, àwọn yóò tún dá ààbò bò ó ti ẹnìkankan kò ní mọ̀ wí pé òun ló sọ fún àwọn.











