NLC ṣe ìwọ́de lórí ọmọ ọdún 22 tí ẹ̀rọ gé lọ́wọ́ ní iléèṣẹ́ tó n bá ṣiṣẹ́

Adekunle Shokunbi

Oríṣun àwòrán, Punch Newspaper

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà (NLC), ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko ti ké pe ìjọba láti wá nǹkan ṣe sí bí ẹ̀rọ iṣẹ́ ṣe ń kó ìpalára bá àwọn òṣìṣẹ́ láì sí àmójútó kankan fún wọn.

Alágá NLC tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko, Funmi Sessi nígbà tó ń ṣọ̀rọ̀ níbi ìwọ́de kan tó wáyé ní Ikorodu lórí i bí ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ṣe gé ọ̀dọ́mọkùnrin kan lọ́wọ́.

Sessi ṣàlàyé pé ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí ní Nàìjíríà tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí yóò máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn lẹ́nu iṣẹ́ òójọ̀ wọn láìní sí ohunkóhun tí yóò ti ẹ̀yin rẹ̀ yọ.

Ó ní àwọn èèyàn mẹ́rin mìíràn ló ti la irú ìṣòrò tí ọmọkùnrin náà ń là kọjá tí ohun èlò iṣẹ́ wọn máa ṣe àkóbá fún wọn lẹ́nu iṣẹ́.

Sessi tó tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní ọ̀nà àti rí owó ilé ìwé ló gbé Adekunle Shokunbi, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) lọ sí ibiṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe oúnjẹ nǹkan ọ̀sìn níbi tí ẹ̀rọ ti ba apá rẹ̀ jẹ́.

“Wọ́n ní láti gé apá náà ni láti èjìká nígbà tí wọ́n gbée dé ilé ìwòsàn.”

Alágá NLC sọ pé bí ìjọba kò bá dá sí ọ̀rọ̀ náà, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò ní yé jáde láti jà fẹ́tọ̀ òṣìṣẹ́ tí ẹ̀rọ kó ìpalára bá.

NLC fi ẹ̀sùn kàn pé àwọn tó ni iléèṣẹ́ npaá pa Adekunle tì, láì náàní rẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Àwọn òṣìṣẹ́ náà ti iléeṣé Spring Seed Feed tí Adekunle ti ṣèṣe ní Itamaga Ikorodu pa tí wọ́n sì tún ti apá kan ọ̀nà márosè Itamaga sí Elepe pa.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi ọmọkunrin naa, Adekunle Shokunbi, ṣe sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin The Punch, o ni ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni iṣẹlẹ to gba ọwọ́ rẹ kan waye.

Adekunle ṣalaye pe ni ọjọ naa, oun n ko awọn ounjẹ adiyẹ to ha si ẹnu ẹrọ, gẹgẹ bi wọn ṣe ma n ṣe, ni akẹẹgbẹ rẹ kan deede tan ina ẹlẹtitiiki si ẹrọ naa.

“Mo n fi ọwọ ko ounjẹ to ku si ẹnu ẹrọ ti a fi n po ounjẹ adiyẹ pọ. Mo si sọ fun gbogbo awọn to wa ninu ileeṣẹ pe mo n ṣe bẹẹ lọwọ, ki ẹnikẹni ma tan ina si ẹrọ.

“Mi o mọ igba ti akẹẹgbẹ mi ọhun lọ tan ina si, ti ẹrọ naa si gba ọwọ rẹ.”

Iya ọmọ naa, Ajoke Shokunbi, sọ pe ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo LUTH, ni wọn ti ṣe iṣẹ abẹ fun ọmọ naa

Bakan naa lo sọ pe owo to to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira ni awọn na.

Nibẹ ni awọn dokita ti ṣalaye fun awọn ẹbi pe, gige ni wọn o ge ọwọ Adekunle, ti wọn si pada ge e.

Arabinrin Shokunbi sọ pe lati igba ti wọn ti pada sile lẹyin iṣẹ abẹ, ni ọmọ oun ko ti fi idunnu gbe igbeaye rẹ mọ.

Adekunel funra rẹ sọ fun akọroyin Punch pe nkan to ṣẹlẹ ti ba awọn erongba rere ti oun ni fun ọjọ iwaju jẹ.

O ni ipinnu oun ni lati fi owo iṣẹ ti oun n ṣe lọ si ile ẹkọ.

Lọwọlọwọ, awọn obi Adekunle Shokubi, ti gbe ẹni to ni ileeṣẹ naa, Arabinrin Dayo Seriki lọ sile ẹjọ.

Bakan naa ni BBC n gbiyanju lati ba igun mejeeji sọrọ.