Omi gbé ọmọ ìjọ mẹ́jọ lọ, mẹ́sàn-án kú níbi ìjọ́sìn ààrin odò

Inu odo yii ni wọn ti n gbadura

Oríṣun àwòrán, ROBERT MULAUDZI

Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ adoola bẹrẹ iṣẹ pada ni owurọ ọjọ Aiku lẹyin ti wọn dawọ duro nirọlẹ ọjọ Satide

Ko din ni eeyan mẹsan-an to ti ku, ti mẹjọ si di awati, lasiko ti ẹkun omi gbe awọn olujọsin lọ leti odo kan ni South Africa.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe awọn ọmọ ijọ naa to le ni ọgbọ̀n duro lori awọn apata to wa ninu odo Jukskei, lasiko ti omi ru kọja lọdọ wọn.

O ni ori ko pasitọ yọ nitori bo ṣe dirọ mọ ẹka igi kan to wa nitosi lasiko ti omi n gbe oun funra rẹ lọ.

Lati igba naa si ni awọn oṣiṣẹ adoola ti n wa awọn ti omi gbe lọ titi di owurọ ọjọ Aiku.

Awọn ọlọpaa, oṣiṣẹ panapana ati awọn akọṣẹmọṣẹ adoola ẹmi ninu odo, lo n siṣẹ karakara lati doola ẹmi awọn eeyan naa.

Agbẹnusọ fun ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri niluu Johannesburg, Robert Mulaudzi, sọ fun awọn akọroyin pe ọjọ Satide ni wọn kọkọ ri oku eeyan meji, ki wọn tun to ri meje mii lowurọ ọjọ Aiku.

Ẹnikan lara awọn ọmọ ijọ to n kopa ninu ijọsin naa, Victor Ncube, sọ fun ileeṣẹ iroyin eNCA pe eeyan marun-un ni oun ri fa jade ninu odo naa, lẹyin ti omi ti gbe wọn rin to ọgọrun mita.

O ni amọ omi ti gbe awọn to ku jina, eyi to mu ko nira lati doola wọn.

Awọn alaṣẹ sọ pe eeyan mẹjọ ni wọn o ti i ri ninu awọn mẹtalelọgbọn to wa nibi ijọsin.

Odo Jukskei ma n ni ẹkun omi asiko òjò lorilẹ-ede South Africa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post