'Èmi ni mo dáńgájíá jùlọ nínú gbogbo àwọn olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà'

Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Bola Ahmed Tinubu ti sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń wádìí rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ sì tún máa ń sọ òkò ọ̀rọ̀ si.
Tinubu ní nítorí wí pé òun ni òun léwájú nínú àwọn tó ń díje sípò ààrẹ Nàìjíríà ni àwọn ènìyàn ṣe ń ṣe ìkọlù sí òun pẹ̀lú onírúurú ọ̀rọ̀ àti àtakò.
Àwọn nǹkan tí máa ṣe fún Nàìjíríà nìyí tí mo di ààrẹ
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí òun tí òun máa ṣe tí òun bá di ààrẹ, Tinubu ní ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé ló jẹ òun tí yóò gbájúmọ́ tóun bá wọlé ìbò lọ́dún 2023.
Bákan náà ló ní òun yóò ri dájú pé òun pèsè iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn àti mú ọ̀wọ́n gógó dínkù jọjọ kí ayé le dùn-ún gbé fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Tinubu sọ pé ètò ìpèsè owó nílò àtúntò ní Nàìjíríà àti pé ìrànwó orí epo bẹntiróòlù nílò kí wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀ kí wọ́n tó yọ ọ́.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ètò ààbò, Tinubu ní òun yóò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sẹ́ka iléeṣẹ́ ológun láti kojú ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra.
Ó fi kun pé ìṣèjọba òun máa yàtọ̀ sí ti Ààrẹ Muhammadu Buhari nítorí ìrírí tí òun ti ní nígbà tí òun ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko máa ran òun lọ́wọ́ láti gbé Nàìjíríà dé èbúté ògo.
Ó tẹ̀síwájú pé òun tukọ̀ ìpínlẹ̀ Eko débi tó jẹ́ wí pé Eko le dá dúró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè fúnra rẹ̀ kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú ló ń takò òun nígbà náà.
Tinubu tún fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrẹ Buhari gbìyànjú agbára rẹ̀, síbẹ̀ àwọn nǹkan tí òun yóò ṣe bí òun bá di ààrẹ yóò yàtọ̀ gédégédé sí ti Buhari nítorí èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní àwọn
Ogún tí mo jẹ lọ́dọ̀ àwọn òbí mi ló sọ mí di ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ
“Àwọn òbí mi fi ohun ìní tó pọ̀ kalẹ̀ fún mi, àwọn nǹkan ni mo ṣiṣẹ́ kún tó sọ mí di ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ lónìí.”
“Mi ò sọ wí pé mi ò lọ́rọ̀ tó pọ̀, kódà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àjọ ló ti ṣèwádìí ìdí ọlà mi tí wọn kò sì ri pé mo ní ẹbọ lẹ́rù."
Tinubu sọ wí pé láti ìgbà tí òun ti kúrò níjọba ìpínlẹ̀ Eko, òun kò gba iṣẹ́ tàbí gba ipò kankan láti ọdún 2007 dí àsìkò.
Ó fi kun pé ìlara ni gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ wí pé òun ń gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe ìjọba lẹ́yìn tí òun kórò nípò.
Ó tẹ̀síwájú pé ìgbà tí àwọn ènìyàn náà sì ti ń gbé ìròyìn elẹ́jẹ̀ yìí, kò sí ẹni tó rí ẹ̀rí mú jáde láti fìdí ọ̀rọ̀ wọn múlẹ̀ kódà lẹ́yìn tí àjọ IMF ṣèwádìí ìpínlẹ̀ Eko.
Kò sí ẹni tó pegede tó mi nínú àwọn olùdíje sípò ààrẹ Nàìjíríà
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn tí wọ́n jọ ń díje sípò ààrẹ Nàìjíríà, Tinubu ní òun ló dáńgájíá jùlọ nínú gbogbo àwọn olùdíje.
Tinubu ní Atiku àti Peter Obi kò yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn yóòkù tó ń díje nítorí náà bí òun kò bá gbégbá ìbò kò sí ẹni tí òun yóò dìbò fún nínú wọn.
Ó ní kò sí ẹni tó ní ìrírí àti àwọn nǹkan tó yà wọ́n sọ́tọ̀ nínú àwọn méjéèjì.












