Àì sí isẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ jẹ́ ọ̀kan gbòógì tó fà ìgbésùnmọ̀mí ní ẹkùn àríwá ìwọ̀ oòrùn- Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Others
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ni ai si isẹ fún pupọ awọn ọdọ ni ẹkun ariwa ìwọ oorun Orilẹede Naijiria lo fa bii igbesunami ati ijinigbe ṣe wọpọ.
Obi pupọ awọn ọdọ ọhun ni wọn ko ni ounjẹ lati jẹ tabi ile gbe fun awọn mọlẹbi wọn.
O sọ eleyi nigba to ṣe Ipada pẹlu awọn olori lati ẹkun ariwa ìwọ oorun niluu Abuja.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni pẹlu anfani ilẹ to wa ni ẹkun naa, o ni wọn ní anfani lati bọ Orilẹede Naijiria pẹlu ohun ọgbin, tí wọn si tun ni anfaani lati bẹrẹ karakata lọ si oke okun.
O ni ti wọn ba fun ohun ni anfani lati di aarẹ lọdun 2023, gbogbo ileri ni ohun yoo mu wa si ìmusẹ
O tẹsiwaju pe ọrọ eto abo to mẹyẹ ni agbegbe naa yoo di ohun igbagbe tí awọn ọdọ agbegbe ọhun baa bẹrẹ si ma ṣe isẹ, tí wọn yoo si wulo fun Orilẹede ati agbegbe wọn.
"Ida aadọta awọn ọdọ ni ko isẹ ni agbegbe yii, ogunlọgọ awọn ọdọ ni wọn ko ọjọ orí tí wọn wa fi wulo lai ṣe nkankan, tí wọn ko si mọ ibi tí oúnjẹ yoo ti wa.
Eyi lo fa rogbodiyan ni agbegbe ariwa ìwọ oorun.
"Nkan ti emi ati Datti ṣe ileri fun yín nipe, akọkọ, a ni ariri to peye lati fi koju awọn ìṣoro yii, tí ẹ sì le gbe ọkan le wa pe a jaabọ fun yín.
Ẹ maa jẹ ki ẹnikẹni sọ fun yin a ko le ṣe atunse si awọn ìṣoro wọnyi, a le ṣe, a sì gbọdọ ṣe kiakia.
"A fẹ mu isọkan ba Orilẹede Naijiria, a fẹ ki orí àwọn ọmọ wa wu pe awọn ti Orilẹede Naijiria wa.
A fẹ gbe Naijiria koro níbi to wa bayi, kí a si yoo awọn eeyan kuro ninu isẹ."















