Ilé ẹjọ́ rán igbákejì Ààrẹ Argentina lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà lórí ẹ̀sùn àjẹbánu

Cristina Fernández de Kirchner

Oríṣun àwòrán, @ben_kew

Ile ẹjọ kan ni Argentina ti ran igbakeji Aarẹ orilẹ-ede naa, Cristina Fernández de Kirchner lẹwọn ọdun mẹfa lẹyin to jẹbi ẹsun ajẹbanu.

Wọn ni Fernández, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọrin lu jibiti pẹlu ipo rẹ lẹyin to gbe akanṣẹ isẹ kan fun ọrẹ rẹ.

Amọ o ṣeeṣe ko má fi oju kan ọgba ẹwọn naa rara.

Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ ọhun, Fernández sọ pe ẹsun ti wọn fi kan ohun lọwọ oṣelu ninu, o si juwe ara rẹ bii ẹni ti awọn alagbara kan n gbogun ti.

Ikọ olupẹjọ ti kọkọ bẹbẹ pe ki ile ẹjọ ran obinrin naa lẹwọn fun ọdun mejila gbako ki ile ẹjọ to dajọ ẹwọn ọdun mẹfa fun.

Ṣaaju ni obinrin naa ti fẹsun kan ikọ olupẹjọ ọhun pe wọn mọọmọ n parọ mọ ohun ti wọn si n gbiyanju lati ba orukọ oun jẹ.

Idajọ yii ni igba akọkọ ti ile ejọ Argentina yoo ran igbakeji Aarẹ lẹwọn lasiko to ṣi wa lori oye lọwọ.

Bi ọrọ naa ṣe ṣẹ

Ikọ olupẹjọ sọ pe Fernández ti fi akoko igba kan ṣe magomago lasiko ijọba rẹ gẹgẹ bii Aarẹ Argentina laarin ọdun 2007 si 2015.

Wọn ni o da eto kan silẹ, eyii to n lo lati gbe akanṣẹ iṣẹ ijọba fun ọrẹ rẹ kan ti iyẹn naa si n ṣe ọwọ kuduru fun.

Bẹẹ naa ni wọn tun fẹsun kan ọrẹ rẹ naa to jẹ oniṣowo, Lázaro Báez, pe oun lo jẹ mundunmudun to pọju ninu ọrọ naa.

Ile ẹjọ ti wa sọ Lázaro Báez si ẹwọn ọdun mẹfa bayii bo tilẹ jẹ pe o ti kọkọ jẹbi ẹsun kan ti wọn si ran lẹwọn ọdun mejila ṣaaju lọdun to kọja.

Apapọ awọn ti wọn jẹjọ naa jẹ mọkanla.

Meje ninu wọn lo jẹbi ẹsun naa ti wọn fi kan wọn, ti wọn si ri ẹwọn to jẹ laarin ọdun mẹta abọ si mẹfa he, wọn da mẹta silẹ nigba ti wọn da ẹjọ ẹnikan nu.