Lamido Sanusi: Emir Kano ní fífẹ́ ju ìyàwó kan lọ ló mú ìṣẹ́ àti ìfàsẹ́yìn ba àpá àríwá Nàìjíríà

Abdullahi Ganduje ati Lamido Sanusi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lamido Sanusi

Laisi ani-ani, aṣa fifẹ ju iyawo kan lọ midi abajọ oṣi ati iṣẹ to wọ pọ lapa ariwa orilẹede Naijiria.

Emir ilu Kano, Muhammad Sanusi Keji lo sọrọ yii nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade fasiti ijọba apapọ niluu Gusau eyi to jẹ alakọọkọ iru rẹ.

Sanusi fọrọ naa lede nigba to ṣe amojuto iwe apilẹkọ kan ti Ọmọwe Usman Bugaji ka nibi ayẹyẹ ikẹkọọgboye fasiti ọhun nipinlẹ Zamfara.

Emir Kano lai jẹ pe awọn eeyan lapa ariwa Naijiria yipada pẹlu aṣa fifẹ ju iyawo kan lọ, o ni oṣi ati iṣẹ to n ba ọpọ finra ko le tan.

O ṣalaye pe ọpọ ọkunrin ni ko le da iyawo ṣoṣo bọ ṣugbọn o ni iyawo mẹta pẹlu awọn ọmọ bakan naa.

O ni iru wọn ko le pese ounjẹ tawọn ọmọ naa yoo jẹ ka to wa sọ pe wọn lowo lọwọ latyi ran awọn yii lọ si ileewe

Lamido Sanusi

Oríṣun àwòrán, Faceboo/Lamidi Sanusi

Sanusi ni lẹyin awọn ẹkun yoku lapa ariwa Naijiria yoo maa wa ayafi ti wọn ba yi aṣa naa pada.

''Ida ọgọrin ninu ọgọrun un awọn eeyan to wa lapa ariwa Naijiria lo n ba iṣẹ finra, nigba ti ida ogun pere wa ni apa gusu,'' Sanusi lo woye bẹẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe ọpọ lo bimọ ti wọn ko tọju wọn, iru awọn bẹẹ lo n tọrọ bara kiri lati le jẹun.

Sanusi ni kekere lawọn ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii bi ikọlu ẹgbẹ agbesunmọmi, Boko Haram, awọn adigunjale ati airiṣẹṣe nitrori yoo buru si nibi ogun ọdun tabi ọgbọn ọdun lọjọ iwaju.