World Education Day: Wo ọmọ ogún ọdún tí kò lè ka lẹ́tà ''A'' dé ''Z''

Aliyu Mohammed

Ọjọ Ẹti, Ọjọ Kẹrinlelogun, Oṣu kinni lọjọ ti ajọ iṣọkan agbaye ya sọtọ fun ayajọ eto ẹkọ lagbaaye.

Abba Haladu to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ to ri si eto mọọkọ mọọka ni Naijiria ṣalaye pe eeyan to to ọgọta miliọnu ni ko mọọkọ mọọka ni Naijiria.

Ọgbẹni Haladu ni orilẹede Naijiria go le goke agba di eto ẹkọ ko ba gbe pẹlẹ si ju bi o ti wa lọ lasiko yii.

Ẹwẹ, Aliyu Mohammed, olugbe ilu Kano to jẹ ọmọ ogun ọdun ni iwadii BBC fihan pe ko le ka ''A'' de ''Z'' ninu lẹta Ede Gẹeṣi.

Mohammed sọ fun BBC pe ko kuku dun mọ oun naa ninu pe oun ko le ka lẹta Gẹẹsi le ka ''A'' de ''Z.''

Nigba ti akọroyin BBC ṣi iwe fun Mohammed ṣugbọn o sọ pe oun ko le ka mọ ohun to wa nibẹ.

Aliyu Mohammed

Mohammed ni awọn obi oun ko fi oun sile iwe, eleyi to maa n mu oun jowu awọn to lọ si ile iwe.

''Mi o wọ yara ikawe ri lati igba ti wọn ti bi mi, ṣugbọn o maa wu mi ko jẹ pe emi naa le kawe bawọn to lọ si ile iwe ṣe maa n ṣe,''Mohammed lo woye bẹẹ.

Awọn onimọ sọ pe o yẹ ki Mohammed lọ kẹkọọ lawọn ibi ti wọn ti n ṣe idanilẹkọọ agba.

Amọ, Mohammed sọ pe oun ṣetan lati lọ kẹkọọ ti wọn ba le kọ oun lọ fẹẹ.