Nigeria Election: INEC yóò ṣàmúlò ẹ̀rọ ayélujára láti fi gba fọ́ọ̀mù àwọn olùdíje

Mahmoud Yakubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mahmoud Yakubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ eleto idibo lorileede Naijiria, INEC sọ pe awọn yoo se amulo ẹrọ ayelujara lati fi gba fọọmu pada lẹyin tawọn to fẹ ẹ dije dupo ninu eto idibo Gomina ipinlẹ Edo ati Ondo ba buwọ lu wọn tan.

Ninu iwe asẹ kan ti ajọ naa fi sita lorukọ alaga wọn, Yakubu Mahmood, wọn ni igbesẹ lilo ilana yii lati fi gba fọọmu pada jẹ ọna lati mu adinku ba ewu itankalẹ arun Covid-19.

Bẹẹ naa ni ilana yi yoo kan titọ pinpin iye owo ti awọn ẹgbẹ oselu ba naa fi se ipolongo, ati iye ti wọn na lati fi orukọ awọn alamojuto eto idibo, ati iwe orukọ awọn asoju ẹgbẹ ransẹ.

Ajọ naa tun sọ pe awọn yoo mu adinku ba iye awọn ti yoo mojuto eto idibo nipasẹ wiwo awọn to sẹ iṣẹ to munadoko ninu eto idibo ti wọn ti se kọja.

''Gbogbo ilana yi wa lati mu adinku ba fifi ara kan ara ẹni, eyi to le mu ki awọn eeyan ko arun Covid-19''

Ba kan naa ni awọn oludibo ati awọn miran to n kopa ninu idibo naa gbọdọ wọ ibomu ti wọn yoo si ya ẹnikẹni to ba safihan apẹẹrẹ Covid- 19 sọtọ.

Ẹwẹ, ajọ naa ti la ilana kalẹ fun eto idibo gomina ni ipinlẹ Edo ati Ondo to fi mọ idibo awọn asojuile asofin.

Agbẹnusọ ajọ naa, Aliyu Bello ni idibo awọn ipinlẹ naa yoo waye ni osu Kẹsan ati osu Kẹwa.

''Ki idibo to bẹrẹ awọn eeyan ni lati jinasirawọn lati le fi dẹkun itankalẹ arun naa. Bakan naa ni ajọ wa yoo pese eroja ipawọ 'hand sanitizer', ti ijiya yoo si wa fawọn oludibo to ba tapa si ilana yi.''

Àjọ INEC ti yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú 74 kúrò l'ágbo òṣèlú Nàìjíríà

Ajọ eleto idibo Naijiria, National Electoral Commission (INEC), ti yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu mẹrinlelaadọrin kuro ni Naijiria.

Ọga agba INEC ati awọn miran nibi ipade ti ikede naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, twitter/Inec

Àkọlé àwòrán, Ọga agba INEC ati awọn miran nibi ipade ti ikede naa ti waye.

INEC kede pe marundinlọgọrin ni awọn ẹgbẹ oṣelu ti ko koju oṣuwọn, ṣugbọn ẹyọkan lara wọn, Action People Party (APP) gbe ajọ naa lọ si ile ẹjọ, to si gba aṣẹ to ka INE lọwọ ko lati yọ orukọ rẹ.

Alaga ajọ naa, Mahmood Yakubu to kede igbesẹ naa fun awọn akọroyin nilu Abuja sọ pe yiyọ ti wọn yọ orukọ wọn kuro wa ni ibamu pẹlu ofin Naijiria.

Awọn ẹgbẹ oṣelu ti ko si l'agbo mọ ni wọn yii:

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu to wa bayii ni yii:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

O sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu naa ko koju oṣuwọn to, wọn ko si ni gbogbo nkan ti ajọ naa n beere lọwọ wọn.

Pẹlu igbesẹ ti INEc gbe yii, ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun pere lo ku.

Kini awọn nkan ti INEC n fẹ, ti wọn ko ni?

Ṣaaju eto idibo gbogboogbo ọdun 2019, ẹgbẹ osẹlu mọkanlelaadọwa (191) lo wa ni Naijiria. Ẹyọkan tun darapọ mọ wọn lẹyin eto idibo na, eyi to sọ ọ di mejilelaadọwa (192).

Ofin Naijiria fun ajọ INEC ni agbara lati yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu yoowu kuro l'agbo oṣelu, ti wọn ko ba ni awọn amuyẹ wọnyii:

  • Tàpá si eyikeyi ninu ilana ti wọn fi n fi orukọ ẹgbẹ oṣelu silẹ
  • Ti ẹgbẹ oṣelu naa ko ba ni ìdá marundinlọgbọn (25%) ninu ibo ti wọn ba di ni ipinlẹ kan ni Naijiria fun ipo aarẹ, tabi ìdá marundinlọgbọn (25%) ninu ibo ti wọn ba di ni ijọba ibilẹ fun ipo gomina ipinlẹ naa.
  • Ti ẹgbẹ oṣelu naa ba kuna lati bori ni wọọdu kan, o kere tan, ninu idibo alaga ijọba ibilẹ; ijoko aṣofin kan nile aṣofin apapọ tabi ipinlẹ; tabi ijoko aṣoju kan ninu idibo kanselọ.

Ṣugbọn ṣa, idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo ni INEC kede pe yoo waye ni ọjọ kẹwa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020. Bakan naa ni ti ipinlẹ Edo yoo waye ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2020.

Awọn atundi ibo kan yoo waye ni ẹkun idibo mẹta nitori iku awọn aṣofin kan ni ipinlẹ Niger, Kwara ati Sokoto.

Ọkọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2020 ni gbogbo atundi ibo naa yoo waye.