Wo àwọn orílẹ̀èdè tó léwájú nínú ìwà àjẹbánu ní àgbáyé lọ́dún 2024

Aworan iwọde to n tako iwa ajẹbanu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n se iwadii nipa titan imọlẹ si iṣejọba lagbaye ti kede iwadii rẹ fun ọdun 2024 lori awọn orilẹede ti iwa ajẹbanu ti wọpọ lagbaye.

Ninu iwadii yii ni awọn amoye ti se ayẹwo orilẹede ọgọsaan, ti wọn si gbe ẹri kalẹ nipa awọn iwa ajẹbanu to n ba orilẹede kọkan ja .

Awọn amoye naa pin awọn orilẹede si isọri, ti wọn si fun wọn ni maaki bẹrẹ lati odo si ọgọrun un.

Orilẹede to ba wa ni odo ni o jẹ pe iwa ajẹbanu n ba wọn n ja, ti awọn to wa ni ọgọrun si jẹ pe wọn ko ni iwa ajẹbanu kankan.

Mọ nipa awọn ti iwa ajẹbanu ko ti wọpọ.

Ọpọ ninu awọn orilẹede ti wọn ko ni iṣoro iwa ajẹbanu nilẹ Yuropu ree.

Meje ninu mẹwaa ni wọn ko ni ibaṣepọ pẹlu orilẹede Russia .

Orilẹede to ni maaki ju ni orilẹede Denmark, pẹlu apapọ aadọrun maaki.

Orilẹede Finland wa ni ipo keji pẹlu maaki mejidinlaadọrun, ti Singapore si wa ni ipo kẹta.

Tabili naa ree

1. Denmark - 90 Maaki

2. Finland - 88 Maaki

3. Singapore - 84 Maaki

4. New Zealand - 83 Maaki

5. Luxembourg - 81 Maaki

6. Norway - 81 Maaki

7. Switzerland - 81 Maaki

8. Sweden - 80 Maaki

9. Netherlands - 78 Maaki

10. Austria - 77 Maaki

Ẹwẹ, iwadii fihan pe ọpọ awọn orilẹede Yuropu ni o gba orinyin ju ninu iwadii

Ọpọ awọn olori orilẹede wọn ni wọn gbaju ohun to se anfani si ọrọ aje ju ohun ti yoo wulo fun araalu.

Awọn orilẹede to n ṣẹsẹ dagba soke

Iwadii fihan pe ọpọ awọn orilẹede to wa labẹ tabili naa lo jẹ orilẹede lati ilẹ Afirika, ti wọn si ni orilẹede mẹfa ninu mẹwaa ti iwa ajẹbanu n ba ja ju.

Orilẹede South Sudan ati Somalia ni orilẹede maji to wa labẹ tabili, ti Sudan si maaki mẹjọ pere nibi ti Somalia ti ni mẹsan an

170. Sudan - 15 Maaki

172. Nicaragua - 14 Maaki

173. Equatorial Guinea - 13 Maaki

173. Eritrea - 13 Maaki

173. Libya - 13 Maaki

173.Yemen - 13 Maaki

177. Syria - 12 Maaki

178. Venezuela - 10 Maaki

179. Somalia - 9 Maaki

180. South Sudan - 8 Maaki

Ipo wo ni orilẹede Naijiria, Niger ati Ghana wa?

Laarin orilẹede Nigeria, Niger ati Ghana, Ghana lo fakọyọ ju, ti wọn si wa ni ipo Ọgọrin lagbaye pẹlu ogoji maaki.

Orilẹede Niger wa ni ipo ẹtadinlaadọfa pẹlu mẹrinlelọgbọn maaki.

Orilẹede Naijiria wa ni ipo ogoje, to si ni maaki mẹrindinlọgbọn pẹlu awọn orilẹede bii Mexico, Iraq ati Cameroon.