Ìyà tí ẹ̀gbọ́n bàbá mi fi jẹ mí ní kékeré ló sọ mí di aláàbọ̀ ẹsẹ̀, ẹrù àrùwọrùn ni kò jẹ́ kí ń ga - Ìyá Gbonkan

Aworan Iya Gbonkan

Oríṣun àwòrán, Iya Gbonkan/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbogbo ohun toju ba ri kọ ni ẹnu le sọ tan.

Agba oṣere, mama Bamidele Olayinka ti ọpọ mọ si Iya Gbonkan, lo sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe laipẹ yii loju opo ikanni Ojopagogo lori itakun agbaye.

Iya Gbonkan ni lati ìbẹrẹ aye oun ni oun ti bẹrẹ iya jijẹ, o ni oun tun jẹ ajẹkun iya lẹnu iṣẹ ere ori itage bakan naa.

Iya Gbonkan, ti i se ọmọbibi ilu Otu nipinlẹ Oyo, ti iya rẹ si jẹ ọmọ ilu Iseyin, ni ipenija pọ loriṣiriṣii lẹnu iṣẹ tiata, o ni diẹ loku ki ipenija ọhun mu ẹmi oun lọ.

"Àwọn Àjẹ́ lù mí lálùbami lójú orun, gbogbo ojú mi wú lójú ayé, lẹ́yìn eré Koto-Ọrun"

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Iya Gbonkan ni "Iya jẹ mi gan an, mo le fori ru apoti aṣọ oṣere fún oṣu mẹrin lai gori itage ere sise rara.

Nigba ti mo sì di ominira ara mi gan an, wọn kìí saba pe mí sí iṣẹ.

Amọ, oloogbe Yekinni Ajileye ni Eledua lo fun mi, nibẹ ni orukọ mi ti jade.

Lẹyìn tí a ṣe fiimu Koto Ọrun ere Ajileye tan, ni awọn ajẹ lu mi lalubami loju orun débi pé gbogbo oju mi lo wu loju aye.

Iya Gbonkan ni lẹyin iṣẹlẹ yìí ni iya kan wa ba oun, to si sọ pe ki oun wa darapọ mọ ẹgbẹ awọn.

Iya Gbonkan kọ jalẹ, o ni Olorun nikan loun mọ.

O ni ori fifọ ti da oun laamu ri lori itage débi wí pe ko sí iru oogun toun ko lo, amọ, ori fifọ naa ko lọ.

Agba oṣere naa ni àwọn ẹbi oun l'Osogbo ni wọn pada tọju oun, ti won ko jẹ ki oun ku.

Iya Gbonkan ni lọdọ ẹgbọn baba oun toun gbe loun ti di alaabọ ẹsẹ pẹlu lilu atigbadegba.

Agba osere naa sọ pe "bo ya mi o ba ga jù báyìí lọ, amọ ẹgbọn baba mi ti lù mi ju.

Bakan naa ni ẹru riru pọju tori ọtika ni egbon baba mi naa n ṣe nigba naa niluu Otu.

Wọn lo mi bi ẹru tori emi nikan ni iya mi bi fun baba mi, orogun ni ko jẹ ki maami duro."

Bayii ni Iya Gbonkan ṣe bẹrẹ ere ori itage ati awọn ọga rẹ lagbo tiata

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iya Gbonkan tẹsiwaju pe, ''Bi mo ti bẹrẹ ere ori itage ni pe lọdọ ẹgbọn baba mi ni mo n gbe, nigba ti baba mi gangan an wa niluu Ibadan.

Amọ, wọn n fiya jẹ mi nibi ti mo n gbe debi wi pe awọn eeyan to ri mi, lọ sọ fun baba mi niluu Ibadan wi pe, iya n jẹ mi nibi ti mo n gbe,'' Iya Gbonkan salaye.

Iya Gbonkan ni bayii loun se sa kuro l'ọdọ ẹgbọn baba oun, toun si mori le ilu Ibadan lati lọ ba baba oun.

Agba osere naa ni lẹyìn toun dé ilu Ibadan, ni oun bẹrẹ sí ní ṣíṣe ọmọ ọdọ.

"Lẹyìn náà ni wọ́n sọ fun mi pe asiko ti to fun mi lati lọ ile ọkọ.

Bayii ni won ti mi mọ inu ile kan wí pe níbẹ ni mo maa wa titi di ọjọ ti mo maa lọ ile ọkọ.

Lẹyin ti mo lo ọjọ mẹsan an ninu naa ni mo sọ fún wọn pe mo fẹ yagbẹ, ti mo si gba ibẹ salọ," Iya Gbonkan salaye.

Bayii ni Iya Gbonkan gba inu igbo de agbegbe Kudeti lọdọ oloogbe ogbontarigi onitiata Duro Ladipo.

Iya Gbonkan ni "Duro Ladipo ni ọga mi akọkọ ninu iṣẹ tiata.

Lẹyìn ti mo lo odun mẹrin ati àbọ pẹlu rẹ, ni mo tun lọ sọdọ Kola Ogunmola l'Osogbo.

Ṣugbọn lẹyin ọdun mẹfa níbẹ ni Ọga Kola Ogunmola ku."

Iya Gbonkan tun gbera lọ sọdọ Baba Oyin Adejobi niluu Osogbo lati tẹsiwaju ninu iṣẹ tiata to yan laayo.

Ọrọ ṣe bi ija laarin Baba Adejobi ati Arabinrin Olayinka, ni Iya Gbonkan ba tun kuro níbẹ lọ sọdọ Baba Ogundipe.

Ju gbogbo rẹ lọ, Iya Gbonkan dupẹ lọwọ Ọlọrun fun gbogbo ilakọja rẹ lagbo ere tiata.

Agba oṣere naa dupẹ lọwọ Eledumare wi pe oun si wa laye wa laaye lẹyin gbogbo nkan ti oun ti la kọja.

Iya Gbonkan ni oun to wa lọkan oun bayii ni pe ki Olorun foun ni ẹmi gigun ati oore ọfẹ, ki o si ran awọn alaanu si oun lati pari ile ti oun kọ lọwọ.

Iya Gbonkan ni o wu oun naa lati fi mọto ṣẹsẹ rin, amọ, ile toun n kọ lo jẹ oun logun julọ bayii.