Kí ni pàtàkì orí òrìṣà Ọ̀ṣọ́ọ̀ṣì, tí ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ààfin Ife, tí Ooni má bọ lọ́dọdún?

Àkọlé fídíò, Kí ni pàtàkì orí òrìṣà Oshoosi tí Ooni má bọ lọ́dọdún?
Kí ni pàtàkì orí òrìṣà Ọ̀ṣọ́ọ̀ṣì, tí ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ààfin Ife, tí Ooni má bọ lọ́dọdún?

Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ro pe ori eeyan ni Ọọni n gbe kiri to ba ti di asiko ọdun Ogun Ọṣọọṣi, ṣugbọn ohun to wa lẹyin ọfa o ju eje lọ.

N jẹ ẹ tiẹ gbagbe pe Ọba alade kankan ko gbọdọ foju kan oku?

Ki wa lo de ti Ooni se maa n gbe ere to da bii oku kiri lasikodun Ogun Ọsọọsi naa?

Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣabẹwo si aafin Ọọni ti Ilu Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Keji, ti ori ade naa si ṣalaye idi ti Ooṣa yii fi ṣe pataki si Ilu Ile Ifẹ.

Aworan Ooni ti ilu ile ife bo o se n da ọti si ori Ọshọọsi

"Ọṣọọsi jẹ ẹbọra, to n daabo bo Ogun Alade, ẹmi rẹ si wa ninu laafin"

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ooni fidi rẹ mulẹ pe Ọṣọọṣi jẹ ẹbọra, to si jẹ oludabobo Ogun alade, ti ẹmi rẹ si wa ninu laafin.

"Ọṣọọṣi,ni a n pe ni Ọba Jẹgijẹgi. Ọdun Ọṣọọṣi naa ni a maa kọkọ se bi ọdun kekere, ka to ṣe ọdun orisa nla.

"Olodumare fun ni agbara pupọ pupọ, ti a n si pe ni Ọba Jẹgijẹgi ni Ife Oodaye.

"Aburo Ogun ni Ọṣọọṣi, oun lo n daabobo orisa nla, to si tun dabobo Ọlọfin."

Obalesun Aṣẹ Obatala, Olaolu Okanlawon Dada, naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa pataki orisa Ọṣọọṣi si ilu Ile Ife.

Bakan naa, o jẹ ko di mimọ pe ko si Ooni to le jẹ, ti ko ni wa tẹriba fun Ọṣọọṣi.

"Ara majẹmu ti Ooni se ni pe yoo ma tọju Ọṣọọṣi, lọdọdun"

Ori Orisa Oshoosi