Ìjìyà tó wà fún ọ tí o bá ń wo fíìmù ìbálòpọ̀ nínú ààwẹ̀ Ramadan rèé

Aworan ẹni to n wo aworan lori foonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ti eeyan ba n gba aawẹ Ramadan gẹgẹ bii Musulumi ododo, igbagbọ awọn eeyan nipa rẹ ni pe ẹni naa yoo kóra ró fun ounjẹ, mímu ati ibalopọ lasiko aawẹ, nitori awọn opo aawẹ gbigba niyẹn.

Ṣugbọn o, awọn nnkan kan maa n ṣẹlẹ ti awọn alawẹẹ, paapaa awọn ọdọ inu wọn yoo maa wo fiimu ibalopọ, boya nitori wọn ro pe yoo jẹ ki ọjọ tete lọ.

Awọn miran lero pe yoo jẹ ki ọkan awọn kuro nibi aijẹun ati ongbẹ, tabi ko si fun awọn ni imọlara ohun teeyan maa n ri to ba n wo ere ifẹ laarin akọ atabo.

Ibeere ni pe ki gan-an lohun ti ẹsin Islam sọ nipa awọn eeyan to n hu iru iwa yii?

Malama Habiba Yahaya Alfadarai, obinrin onimọ nipa ẹsin Islam niluu Abuja, ṣalaye fun BBC pe wiwo fiimu ibalopọ ninu aawẹ ko ba aawẹ jẹ, bo tilẹ jẹ pe eewọ ni.

O ni ṣugbọn wiwo fiimu ibalopọ ninu aawẹ maa n din laada alaawẹ ku, o si le pada ja si pe ẹni ọhun ko gbaawẹ rara.

Alfadarai sọ pe, " wiwo ere ifẹ atawọn iwokuwo bẹẹ lodi ninu Islam, Allah sọ fun ojiṣẹ nla Anọbi Muhammad (Ike ati ọla Ọlọrun ko maa ba a) pe ko sọ fawọn olugbagbọ ododo, pe oun ṣe iwokuwo leewọ fun wọn, yala eyi to han abi to pamọ"

" Aaya Al-Quran ti Anọbi (Ikẹ ati ọla Ọlọun maa ba a) ti sọ pe awọn Musulumi ododo gbọdọ diju si iwokuwo wa. Bẹẹ lo si pa wọn laṣẹ lati da aabo bo oju ara wọn.

" Ẹni to ba n gbaawẹ to tun n wo iwokuwo, oju rẹ ko gbaawẹ. Bẹẹ, gbogbo ẹya ara lo yẹ ko gbaawẹ titi to fi de ẹsẹ.

Aawẹ oju ni pe eeyan ko gbọdọ wo iwokuwo, koda ko ma jẹ asiko aawẹ, keeyan ma si fẹnu rẹ sọ isọkusọ.

Èwo la lè pè ní fíìmù ìwòkuwò àbí ti ìbálòpọ̀?

Hajia Habiba tẹsiwaju pe fiimu to ba ti ṣafihan ihoho, ti wọn tun n sọ awọn ọrọ to le mu ara eeyan maa fa si ere ifẹ, iwokuwo ni.

" Ohun yoowu t’Ọlọrun ti paṣẹ fun wa lati bo, tabi to ni ka ma sọ nipa ihoho ati oju-ara, ti eeyan ba ti n sọ ọ, isọkusọ lo n sọ, iwokuwo lo n wo, iṣekuṣe lo n ṣe."

‘’Ìwòkuwò lè mú ọ dáràn ààwẹ̀ ọgọ́ta ọjọ́’’

" Teeyan ba wo fiimu iwokuwo titi to fi da nnkan sara bii àtọ̀, nitori ohun to n wo naa ti n wu u lati ṣe, aawẹ iru ẹni bẹẹ ti já.

‘’To ba ti ṣẹlẹ bayii, yoo gba aawẹ ọgọta (60) pada, yoo si tun gba ẹyọ kan to fi wo iwokuwo to si bajẹ naa pada pẹlu.

Bayii naa lo ṣe ri fun ẹni to mọ-ọn-mọ ja aawẹ rẹ ninu Ramadan, to jẹun tabi ṣe ohun to lodi, lai si idi kan fun un lati ṣe bẹẹ.

" Bi nnkankan ko ba jade lara rẹ nitori ohun to wo tabi gbọ, aawẹ naa ko tori ẹ ni alaafia naa.

A le sọ pe aawẹ to labawọn lẹni naa gba, ẹṣẹ nla lo si da niwaju Ọlọrun pẹlu’’

Bayii ni Malama Habiba Alfadarai ṣalaye.

Aworan ẹni to n wo aworan lori foonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

’’Àwọn ohun tí aláàwẹ̀ nílò’’

  • Kika Kurani, eyi maa n jẹ ki laada aawẹ pọ, nitori ibukun rẹ.
  • Riranti Oluwa nipa titọrọ aforiji, ṣiṣe Asalatu fun Ojiṣẹ nla Muhammad (Ki ikẹ ati ọla Oluwa maa ba a) ṣiṣe Lailah- Ilaalah ati ọpọlọpọ Tasbihi.
  • Fifun awọn eeyan lounjẹ ọfẹ, eyi to ni ibukun ailailẹgbẹ ninu.
  • Jiji kirun loru. Kiki Tarawih ta a tun mọ si irun Aṣaamu. Laada wọn ko ṣee ka.
  • Kiko ẹnu eeyan nijaanu: Alaawẹ ko gbọdọ purọ, beeyan ko gbaawẹ paapaa, eewọ nirọ pipa ninu Islam.
  • Lilọ sibi waasi ododo ti wọn yoo ti gbọrọ Allah, nibi teeyan yoo ti mọ ohun ti Oluwa fẹ ateyi to ṣe leewọ.

Lakootan, Aafaa Maraya sọ pe ohunkohun teeyan ba ti mọ pe yoo ba aawẹ oun jẹ, keeyan fi i silẹ lasiko Ramadan yii ni.

O ni asiko ti eeyan maa n kọ ọkan ati ara rẹ lati sunmọ Ọlọrun gidi ni asiko Ramadan, igbagbọ wa pe ẹkọ ti alaawẹ kọ ninu Ramadan to si mu lo, yoo maa lọ bẹẹ titi opin aye rẹ.

Iṣẹ oloore ati jijẹ ẹni Oluwa ko pari si Ramadan nikan bi iwe mimọ Alkurani ṣe sọ.