Ọkùnrin táwọn dókítà fi kíndìnrín ẹlẹ́dẹ̀ pààrọ̀ kíndìnrín rẹ̀ 'ti ń gbádùn'

Oríṣun àwòrán, Massachusetts General Hospital
Ọkunrin kan ẹni ọdun mejilelọgọta t'awọn dokita fi kindinrin ẹlẹdẹ ṣe ipaarọ kindinrin rẹ ti n gbadun bayii, gẹgẹ bi awọn onimọ iṣegun ṣe sọ.
Awọn dokita ni orilẹede America ni, akinkanju ni Rick Slayman ti wọn ṣe iṣẹ abẹ ọhun fun, eyi to jẹ akọkọ irú rẹ.
Erongba wọn ni lati maa lo kindinrin ẹranko paarọ fawọn eeyan to ba laarun kindinrin.
Awọn dokita ti fi kindinrin ẹlẹdẹ sinu awọn eeyan ti ọpọlọ wọn ti ku ri tẹlẹ.
Ile iwosan Massachusetts ni America sọ ninu atejade kan to fi sita pe, iṣẹ abẹ yii to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024, jẹ ilọsiwaju ninu ọna lati wa kindinrin mii fawọn eeyan to nilo rẹ.
Ẹwẹ, Ọgbẹni Slayman fti kọ́kọ́ ṣe iṣẹ abẹ eyi ti wọn fi paarọ kindinrin rẹ lọdun 2018, nitori kindinrin rẹ ko ṣiṣẹ daadaa.
Amọ, lẹyin ọdun marun un, kindinrin ti wọn fi paarọ kindinrin rẹ da iṣẹ silẹ loṣu Karun un ọdun 2023.
Ailera rẹ bẹrẹ si ni pọ si gẹgẹ bi awọn dokita ṣe sọ.
Bayii lo bẹrẹ itọju araun kindinrin eleyii to jẹ ko maa lọ si ile iwosan lọsẹ meje-meji.
Slayman ni oun ṣe agbeyẹwo bi ara oun ṣe ri ti oun si pinnu lati lo kindinrin ẹlẹdẹ paarọ kindinrin oun.
"Mo ri i gẹgẹ bi ọna abayọ fun mi ati ẹgbẹẹgbẹ̀run awọn mii ti wọn nilo lati paarọ kindinrin wọn lati wa laaye."

Oríṣun àwòrán, Massachusetts General Hospital
Ati ri kindinrin eeyan lati fi paarọ fawọn to ni aarun kindinrin ti n nira gan an.
Lilo kindinrin ẹranko le ṣe iranwọ pẹlu eyi.
Awọn onimọ iṣegun ti ṣe iṣẹ abẹ lilo ọkan ẹlẹdẹ fun eeyan laipẹ yii bakan naa.
Wọn ni ọkan ẹlẹdẹ dabi ọkan eeyan.
Awọn dokita ti ṣe itọju kindinrin ẹlẹdẹ yii lati ri pe ko le fa aisan si agọ ara ẹni ti wọn fẹ fi si.
Ọgbẹni Slayman ṣi n gba abẹrẹ ati oogun lẹyin ti wọn ti fi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ kindinrin rẹ.
Amọ, ko si ẹni to mọ igba ti kindinrin ẹlẹdẹ yii yoo ṣiṣẹ lara Slayman da, nitori igba àkọkọ ree ti iru iṣẹ abẹ yii yoo waye.
Dokita Tatsuo Kawai to jẹ ọkan lara awọn dokita to ṣe iṣẹ abẹ naa sọ pe "ireti wa ni lati maa fi kindinrin ẹlẹdẹ ṣe ipaarọ fun ọpọ eeyan to ni aarun kindinrin l'agbaaye."















