Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó pa Yusuf na pápá bora, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Ilorin

Jẹjẹ lawọn ara adugbo Pakata ni ilu Ilorin n ba bukata wọn lọ lọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, ọdun 2024 ki afurasi ọmọ ẹgbe okunkan to da omi alaafia adugbo wọn ru.
Abiodun ni wọn pe orukọ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun yi ohun to si ṣe ni pe o wọle tọ gende kunrin kan torukọ rẹ n jẹ Yusuf to si ṣeku pa.
Lẹyin ti Abiodun seku pa a tan ni rogbodiyan ba bẹ silẹ, lọrọ ba di ẹni ori yọ, o dile, ọpọ farapa, bẹẹ si ni ọpọ dukia ṣegbe sinu rogbodiyan ti iṣẹlẹ yi mu wa
Àlàyé lórí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé
BBC Yoruba gbọ pe, ni alẹ, ọjọ Ẹti, ni afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn n pe ni Abiọdun, to n gbe ni agboole Ghana (Ghana House), lagbegbe Pàkákà, niluu Ilọrin, yinbọn pa arakunrin Yusuf, to si juba ehoro.
Yusuf yi ni iwadii fihan pe o ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo, iyawo rẹ si tun wa ninu oyun lọwọ lọwọ.
Ọkan lara awọn ara adugbo rẹ sọ pe ija awọn ẹlẹgbẹ okunkun meji lo bẹ ṣilẹ, oun si funra pe Yusuf jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun mii ko to ku.
Gẹgẹ bi BBC Yoruba, ṣe gbọ laaarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta yii, ni awọn ikọ Yusuf ti wọn pa, ya bo agbole awọn Abiọdun, ti wọn n pe ni (Ghana House), lagbegbe Pakata.
Wọn bẹrẹ si ni yinbọn ti gbogbo awọn olugbe agbegbe naa si bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi ara wọn
Ẹni duro gbe, ẹni bẹrẹ daran, gbogbo agbegbe si da paroparo.

Awọn ọmọ janduku yii wọ agboole Ghana lọ wọn si n sa gbogbo awọn ti wọn ri lada, ọpọ lo fara gbọgbẹ bakan naa ni wọn ba ọpọlọpọ dukia jẹ.
Gbogbo mọto ati awọn nkan mii ti wọn ba ni agbegbe naa ni wọn bajẹ
Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ti wọn wa sibẹ, nkan o ba bajẹ jina.
Nigba ti iroyin tẹ wọn lọwọ ni wọn lọ si agbegbe naa, ti wọn si lọọ pana rogbodiyan ọhun.
Ohun to dunni ni pe, gbogbo awọn ọmọ janduku naa lo sa lọ patapata ṣugbọn awọn iya agbalagba to jẹ mọlẹbi Abiọdun ni awọn ọlọpaa n ko lọ atimọle.
Igba ti BBC Yoruba kan si alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, lalẹ Satide, o fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
O ni iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa ati wi pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ipaniyan ati rogbodiyan naa ni awọn yoo fọwọ ofin gbe.












