Èèyàn mẹ́rin kú níbi tí wọ́n ti fẹ́ẹ́ gba ǹǹkan ààwẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Latari bi ebi ati airowona ṣe n ba araalu finra lorilẹ-ede Naijiria lasiko yii, eeyan mẹrin mi-in ni wọn tun ku nibi ti wọn ti fẹẹ gba itọrẹ aanu ẹgbẹrun marun-un nipinlẹ Bauchi.
Ahmed Wakili , Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, sọ fun BBC pe ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹta, 2024 ni awọn eeyan naa tẹ ara wọn pa nileeṣẹ Shafa Holding Company, Bauchi.
O ni ẹni to ni ileeṣẹ naa n pin ẹgbẹrun marun-un naira fun wọn laaarọ ọjọ naa gẹgẹ bi nnkan aawẹ ati itọrẹ aanu, ṣugbọn ero ti pọ ju.
Ọpọlọpọ iyaale ile, awọn ọmọde atawọn agbalagba ni wọn rọ lọ sileeṣẹ naa,
nibi ti wọn si ti n gbiyanju lati gbowo ni wọn ti ba iku pade.
Nnkan bii aago mẹwaa kọja ogun iṣẹju ni rirọgiiri naa bẹrẹ bo ṣe wi, ti wọn fi tẹ ara wọn pa.
‘Ọdọọdun ni ileeṣẹ naa maa n ṣe itọrẹ aanu yii’
Alukoro ọlọpaa Bauchi ṣalaye pe ọdọọdun ni ileeṣẹ naa maa n fun awọn eeyan ni nnkan aawẹ bi eyi.
O ni ero wọn ni lati fi ṣe iranlọwọ fawọn eeyan to ku diẹ kaato fun.
O fi kun un pe eeyan marun-un ni wọn gbe lọ sileewosan ikọṣẹ iṣẹgun Tafawa Balewa, ti awọn mẹrin si ba a lọ.
’’ Bi ẹ ba fẹẹ fun ọpọ eeyan ni nnkan iranwọ bi eyi, ẹ ri i daju pe ẹ fi to awọn agbonfiro leti, ki wọn le ṣamojuto to yẹ nipa rẹ.
“ Eyi to ṣẹlẹ yii, to ba ṣe pe wọn fi to awọn ọlọpaa leti lati ṣakoso rẹ ni, mi o ro pe iru eyi yoo ṣẹlẹ’’ Bẹẹ ni Wakil wi.
'Eeyan mẹtadinlogun lo ku, ki i ṣe mẹrin'
Iroyin kan ti a ko fidi ẹ mulẹ, sọ pe eeyan mẹtadinlogun (17) lo ku ninu iṣẹlẹ naa, mẹrin kọ.
Ọkan ninu awọn ẹṣọ to wa nibi iṣẹlẹ naa ti ko darukọ rẹ, sọ fawọn akọroyin pe oku eeyan mẹtadinlogun lawọn gbe jade.
O ni awọm ọmọdebinrin mẹwaa ati iyaale ile meje ni wọn.
O fi kun un pe ọna jinjin lawọn mi-in ti wa ninu awọn obinrin naa, ti wọn ko awọn ọmọ wa ki owo ti wọn yoo gba le pọ daadaa.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti ti i ṣe ọjọ meji ṣaaju iṣẹlẹ Bauchi yii ni awọn akẹkọọ meji ku ni Yunifasiti ipinlẹ Nasarawa.
Lasiko ti wọn fẹẹ gba irẹsi ati ẹgbẹrun marun-un naira nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade nileewe naa ni wọn tẹ wọn pa.














