Ààrẹ Macky Sall kí Bassirou Diomaye Faye kú oríire ìjáwéolúborí nínú ìbò ààrẹ Senegal

Aworan Bassirou Diomaye Faye

Oríṣun àwòrán, AFP

Olori ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye lorileede Senegal Amadou Ba ti gba pe oun fidirẹmi ninu idibo aarẹ to waye.

Eyi ko ṣẹyin bo ti ṣe fi ọrọ ikinni ku oriire ranṣẹ si alatako rẹ Diomaye Faye ti o sunmọ pe o ti fakọy ninu idibo to waye lọjọ Aiku.

Ninu atẹjade kan to fi sita, o sọ pe ‘’Pẹlu gbogbo awọn esi idibo taa ti ri ti wọn gbe jade, yoo wu mi lati ki aarẹ ti ilu yan, Bassirou Diakhar Diomaye Faye ku oriire aṣeyọri rẹ ninu abala kini idibo ilẹ wa’’

‘’Mo gbadura ki Ọlọrun fun ni okun ati agbara ti yoo fi dari orileede wa’’

Bakan naa ni aarẹorileede naa, Aarẹ Macky Sall ti fi ikinni tiẹ naa ranṣẹ si ẹni to jaweolubori ninu idibo.

Ajọ eleto idibo orileede naa ko ti kede pe Diomaye Faye jaweolubori ṣugbọn awọn esi ti o ti n jade kaakiri tọka si pe oun ni kini naa ja mọ lọwọ.

Loju opo rẹ ni Twitter, X, Aarẹ Macky Sall sọ pe ''Mo kan saara si bi wọn ṣe ṣeto idibo aarẹ lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹta ti ko si ni kọnunkọhọ ninu mo si ki ẹni to jaweolubori Ọgbẹni Bassirou Diomaye Faye ti iroyin tọka pe oun lo n lewaju;''

Macky Sall pari ọrọ ikinni rẹ pẹlu ọrọ pe ''apẹrẹ leleyi jẹ gẹgẹ bi aṣeyọri fun ijọba awarawa ni Senegal''

Yatọ si awọn wọnyii, awọn oludije to ku naa ti fi ọrọ ikinni ranṣẹ si arakunrin Faye.

Ireti wa wi pe ajọ eleto idibo orileede ọhun yoo pari akojọpọ esi idibo toyẹ ko waye laarin ọjọ mẹta ki wọn to kede ẹni to jawe olubori.

Faye ni oludije ti olori alatako Ousmane Sonko ṣatilẹyin fun.

Lọjọ Kẹrinla oṣu yi ni wọn tu Bassirou Faye ati Ousmane Sonko sil ni ahamọ ti wọn wa lẹyin ti aarẹ fori jin wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post