Nasir El-Rufai fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀, ó darapọ̀ mọ́ SDP

Aworan Mallam Nasir El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mallam El Rufai

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ana nipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir Ahmad El-Rufai ti kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ ọselu All Progressive Congress, to si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party.

El-Rufai kede eyi ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta ọdun, 2025.

O ni ẹgbẹ oṣelu APC ti yabara kuro ninu ida pataki ti wọn fi da silẹ lọdun 2013.

Gomina ana ọhun, jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ni oun ti gbiyanju lati sọrọ nipa bi ẹgbẹ oṣelu naa se lọ ni ikọkọ ati ni igangba ṣugbọn awọn to n dari APC kọ lati gbọ ọrọ rẹ.

El- Rufia ni igbagbọ ni pe ero oun ati ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo tubọ tẹsiwaju saaju ko to fẹyinti lẹnu iṣẹ oṣelu ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ

"Lonii, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta ọdun 2025, mo ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ni wọọdu mi nipinlẹ Kaduna ni kiakia.

"Saaju ki n to gbe igbesẹ yii, mo ti kan sawọn to gba mi ni imọran, awọn akẹgbẹ mi kaakiri orilẹede Naijiria nipa ọjọ ọla.

"Mo ti pinnu lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party. "

El Rufai ran awọn ọmọ Naijiria leti pe oun ti se atilẹyin fun APC lasiko ibo Aarẹ ni ọdun 2015, 2019 ati ni 2023, ti oun si ti jẹ Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa fun ọdun mẹjọ.

Sugbọn bayii, APC ti di ẹgbẹ ti ko bọwọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ mọ, ti oun ko si lẹ tẹsiwaju pẹlu ẹgbẹ naa.

"N ko le jokoo sinu ẹgbẹ oṣelu ti wọn ti yọ ifun rẹ, to si n se awọn ọmọ ẹgbẹ bo se wu. Idi ti mo fi pinnu pe ki n gbe erongba mi lọ sinu ẹgbẹ oṣelu SDP niyẹn.

"Mo n kesi awọn alatilẹyin mi ati gbogbo eeyan to fẹ ki Naijiria dara pe ki wọn darapọ mọ w ani ẹgbẹ oṣelu SDP, lati gbe orilẹede Naijiria ga si lẹẹkansi."