Ìjọba àná l'Osun gba owóyàá ogún mílíọ̀nù Dọ́la láti kọ́ ibùdó ìwòsàn alábọ́dé àmọ́ wọn kò ṣe é - Adeleke
Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun lo ti lo ọdun mẹta lori aleefa bayii.
Lasiko ọdun mẹta naa, oniruuru ojo lo ti rọ ti ilẹ ti fi mu.
Ọpọ isẹlẹ lo ti waye eyi to n mu ki wọn maa yonbo gomina ipinlẹ Osun tabi ki ẹnu maa kun un.
Ọna lati lu gomina Adeleke lẹnu gbọrọ lori awọn isẹlẹ to ti waye si ati ipinlẹ Osun laarin Odun mẹta, lo ta BBC Yoruba nidi kan, lati lọ ba nilu Osogbo.
Ọrọ pọ ti gomina ba wa sọ, lara rẹ ni ẹsun pe o maa n jo ju, se o ni baba isalẹ, awọn isẹ idagbasoke to ti se ati pe se awọn ẹbi rẹ lo n dari rẹ gẹgẹ bawọn eeyan kan se n wi.

"Laarin ọdun meji, a ti se ọpọ oju ọna, ko si ilu kankan ni ipinlẹ Osun, ti a ko se oju popo de"
Lasiko ifọrọwerọ BBC Yoruba pẹlu gomina Ademola Adeleke, o salaye pe ọpọ aseyọri ni oun ti se laarin ọdun meji ti oun ti gori aleefa nipinlẹ Osun.
O ni lara isẹ idagbasoke naa ni lila ati atunse oju ọna wa eyi ti ọwọja rẹ na kaakiri ipinlẹ Osun.
"Ní gbogbo ẹka igbe ayé bíi eto ọ̀gbìn, eto ẹkọ, ìpèsè ohun èlò amayedẹrun, ìlera, ṣe ni gbogbo nnkan dàrú nibẹ nigba ta gori aleefa.
Iṣẹ́ náà là bẹrẹ, nígbà tí yóò fi pe ọdún méjì, ó yà wá lẹnu pé a ti ṣe ọna tó tó bayi.
Lẹnu ọdún méjì, a ti ṣe ọna. Lara ilana isejọba òní koko marun ti a ni, eto ọgbin wá nibẹ. Àmọ́ bí kò bá sì ojú ọna tó dára láti oko, báwo ni wọn ṣe fẹ́ gbé oúnjẹ wá sí àárín ìlú.
A wá ń ṣe ọna tó dára káàkiri. Kò sí ìlú ni Osun tó máa ní a kò de ọdọ wọn láti ṣe ọna, a kò sì ya owó."

"Owo Osun ti n gbe Osun, a ko lọ ko awọn onisẹ ọwọ wa lati Eko tabi ilu mioran ko wa sisẹ ni Osun"
Bakan naa, gomina Ademola Adeleke tẹsiwaju pe awọn osisẹ ati onisẹ ọwọ to wa nipinlẹ Osun ti n mọ ipa isejọba rere lara, ti wọn si n ri taje se.
"Nnkan tá kan sọ fáwọn èèyàn wa ni pe owo Osun yóò gbé Osun.
Àwọn tó ń sisẹ ọwọ bíi Plumber, Kafinta, Birikila àti bẹẹ bẹẹ lo wà ní Osun, kí wá lo dé tí a fi máa ko àwọn èèyàn wa lati Eko ati awọn ilu ibomiran.
Ohun tó tún rán wa lọ́wọ́ nìyẹn, tí àwọn owó yìí, tí kò yẹ kí wọn lọ síbi tí kò yẹ kí wọn lọ, mo di í pa. "
"Ijọba ana ni Osun gba owoya ogun miliọnu Dọla lati kọ ibudo ilera alabọde, wọn ko se"
Gomina ipinlẹ Osun, lasiko ifọrọwerọ̀ rẹ, tun mẹnuba pe ijọba oun ko rẹyin lẹka eto ilera, koda wọn se ipo kinni ninu igbelewọn awọn ipinlẹ tp pegede lẹka eto ilera, ti ipinlẹ Osun si gba ami ẹyẹ.
"Nipa ọrọ ìwòsàn, wọn fún wa ní àmì ẹ́yẹ pẹlu owó tó to ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹẹdẹgbẹta dọla torí àwa là ṣe ipò kini.
Owo ti wọn fún wa yìí ni a dá padà sí ẹka eto ìlera lati se awọn isẹ idagbasoke miran nibẹ.
Torí àwa kò ní ṣe bíi àwọn kan, tó jẹ́ pé wọn fún wọn ní owoya ogún milionu dọla, àwọn ìjọba ana, pé kí wọn fi kọ ibudo ìwòsàn Alabọde, a dé ibẹ, wọn kò ṣe é, èyí kò dára rárá."
"N ko ni baba isalẹ, kii si se awọn ẹgbọn mi lo n se bii gomina lati maa dari mi"
Ni ọpọ igba ni ahesọ ọrọ ti lu bọ si igboro pe awọn ẹgbọn gomina Adeleke lo maa n dari rẹ lati se ọpọ ipinnu to n se.
Koda, ahesọ ọrọ naa ni awọn ẹgbọn rẹ yii lo jẹ baba isalẹ fun, ti wọn si maa n se bii gomina nipinlẹ Osun.
Nigba to n fesi lori awọn ahesọ ọrọ yii, Gomina Adeleke ni ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun lawọn ọrọ yii, tori irọ to jinna si ootọ ni wọn.
"Gomina tèmi yàtọ̀, Ọlọrun fẹ́ràn mi, mo sì ní àwọn ẹbí tó dára, èmi kò ní bàbà ìsàlẹ̀ bí mo ṣe wá yìí, n kò sì ní èèyàn kankan tí mo ń dawo padà fún.
Torí rẹ ni gbogbo isẹ ìdàgbàsókè yìí ṣe ń lọ daadaa, torí rẹ lè ṣe rí isẹ.
Wọn máa ń sọ pé àwọn ẹ̀gbọ́n mi, Dupe àti Seyi lo ń darí mi, àwọn lo ń ṣe bíi gomina, èmi ga nkò ṣe bíi gomina.
Gbogbo àwọn tó ń bá mi sisẹ mo pe mo máa ń béèrè ìmọ̀ràn lọwọ wọn.
Àmọ́ tí wọn ba fún mi ní ìmọ̀ràn, tí ń kọ bá fara mọ, kò lè di ohun. Èmi ni mo ní gege ikọwe pupa tí máa fi buwọlu aba wọn.
Tí ẹbi mi àtàwọn olubadamọran mi bá fún mi ní ìmọ̀ràn, tí mo sì rí pé ìmọ̀ràn wọn dára, ṣe kí n máa gba a ní? Ṣé ìyẹn wá sọ pé àwọn ni Gomina ni?
Kò sí gomina tàbí ààrẹ tí kò ní àwọn èèyàn tó ń fún wọn ní ìmọ̀ràn àmọ́ àṣẹ tó gbẹyin, orí tábìlì mi lo wa."
"Mo fẹ́ràn ijo jijo pupọ, láti kékeré ni mo ti máa ń jó, tí mo sì máa ń fi yín Ọlọ́run lógo, mo si maa jo dẹndẹ ijo"
Lara awọn ika aleebu ti awọn eeyan kan tun maa n na si gomina Adeleke ni pe o maa n jo pupọ, Ijolabi si ni wọn sọ ọ tori ki eti rẹ ma tii gbọ ilu ni, yoo ti mu ijo jo.
Amọ se ni gomina Adeleke da siọ ẹsun yii, to si ni wọn ko tii ri nkankan tori oun si maa jo dẹndẹ ijo siwaju si.
"Wọn ṣe é títí bíi kí n máa bàa máa jó àmọ́ wọn tán ara wọn jẹ ní.
Ijo jíjó kò di isẹ mi lọwọ torí onikaluku lo ni nkan tó fẹ́ràn láti máa ṣe.
Àwọn lo mọ àmọ́ èmi yóò jo dẹndẹ ijo, máa sì sisẹ."






