Nnamdi Kanu ti fi ohùn ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Biafra láti àhámọ́ DSS

Olori ẹgbẹ ajijgbara Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati gbogun ti gbogbo awọn to n wu iwa ọdaran lorukọ ẹgbẹ ọhun ni iha Ila oorun Naijiria.
Kanu lo sọ ọrọ naa lasiko ti awọn agbẹjọro rẹ, Mike Ozekhome ati Ifeanyi Ejiofo lọ ṣabẹwo si ni ahamọ ajọ DSS to wa niluu Abuja.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii ni ijọba Naijiria fi tipatikuku gbe Kanu wale lati orilẹ-ede Kenya.
Ejiofor ni Kanu ransẹ si awọn alatilẹyin rẹ ki wọn maa ṣọra fun awọn to lo n lo orukọ IPOB fun iwa ọdaran bi ijinigbe, idigunjale ati ipaniyan nilẹ Igbo.
O ti to gẹ!
Gẹgẹ bii atẹjade to fi lede lou po Twitter rẹ lọjọ Aje, Ejiofor ni Nnamdi Kanu ti kilọ fun awọ alatilẹyin rẹ lati ṣọra fun iwa ọdaran.
O ni “Ẹnikẹni to ba n fi ipa mu awọn eeyan joko sile lasiko to yẹ ki wọn wa nibiṣe wọn jẹ ọta Onyendu Nnamdi Kanu.”
“Aṣaaju wa ko pasẹ pe ki ẹnikẹni maa joko sile lagbegbe Biafra.”
Ti ẹ ko ba gbagbe, IPOB ti ṣe ofin igbele kan lati fẹhonuhan si bi ijọba apapọ ṣe fi ṣikun ofin mu Nnamdi Kanu.
Ejiofor pari ọrọ rẹ pe “Iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran mii jẹ ajoji si awọn eeyan wa, ẹnikẹni to ba si wu irufẹ iwa bẹẹ jẹ ọta araalu ati ọta Nnamdi Kanu.”












