Alákòóso ní Rivers kìlọ́ fáwọn oníwàhálà bí PANDEF ṣe fọnmú mọ́ Tinubu lọ́wọ́ lórí ìkéde ìlú kò fararọ

Oríṣun àwòrán, Fubara/Tinubu
Alakoso tuntun fun ipinlẹ Rivers, ọgagun Ibok-Ette Ibas, ti kilọ fun awọn to fẹ maa fa wahala nipinlẹ naa ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ nitori oun ko ni gba ki ẹnikẹni da ipinlẹ naa ru labẹ iṣẹjọba oun.
Ibas lo fi ikilọ naa lede lasiko to n ba awọn eeyan ipinlẹ ọhun sọrọ lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu burawọle fun un.
Ọgagun naa ni oun ko gba lati ṣe alakoso Rivers lọna ati wa lori ipo aṣẹ amọ lọna ati pa ina rogobodiyan to yẹ ko bẹ silẹ nipinlẹ ọhun.
O ni "Ojuṣe mi ko farasin rara, o jẹ lati da ofin ati alaafia si aarin ilu ki a si ṣe ohun to tọ lati da ijọba pada fun oloṣelu.
"Iṣẹ yii kii ṣe iṣẹ ẹnikan, aṣeyọri wa yoo da lori ifọwọsowọpọ gbogbo awọn eeyan Rivers – awọn agbalagba, olori oṣelu, awọn baalẹ, awọ ọdọ, awọn obinrin, awọn akọroyin atawọn araalu mii."
Ibas sọ siwaju si pe oun kii ṣe oṣelu, oun ko si lọwọ ninu rogbodiyan to bẹ silẹ nibẹ amọ oun wa sin awọn eeyan ipinlẹ naa ni.
Lẹyin naa lo ṣeleri lati ṣiṣẹ takuntakun laarin oṣu mẹfa ti Aarẹ fun oun lori alefa lati ṣe ohun to yẹ ki rogbodiyan ipinlẹ naa le di oun igbagbe ki alafia si jọba nibẹ.
Tinubu gbọdọ da Fubara sori ipo rẹ ni kankan - Ẹgbẹ awọn gomina PDP
Ẹwẹ, awọn gomina ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni Naijiria, PDPGF, ti ṣeleri lati pe Aarẹ Tinubu lẹjọ lori bo ṣe kede ilu o fararọ ni Rivers to si da gomina atawọn aṣofin ipinlẹ naa duro.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina naa to tun jẹ gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed sọ ninu atẹjade kan pe awọn gomina ọhun ti ke si Aarẹ Tinubu ko yi igbesẹ naa pada ni kankan.
Atẹjade ọhun sọ pe "A duro digbi lẹyin gomina Siminalayi Fubara atawọn eeyan ipinlẹ Rivers lasiko iṣoro yii.
"Aarẹ, a fẹ ki ẹ mọ pe a mọ bi ẹ ṣe dakẹ gbera lori ipa ti minisita yin fun FCT ko ninu rogbodiyan yii."
Lẹyin naa ni wọn rọ Aarẹ ko yi igbesẹ naa pada ko to pẹ ju.
Mi o mọ nkankan nipa awọn to ju ado oloro si ọpa epo – Fubara
Gomina ti Aarẹ da duro ni Rivers, Similanayi Fubara, ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti ijọba apapọ fi kan oun ninu ọrọ rẹ to ba awọn araalu sọ.
Agbẹnusọ Fubara, Nelson Chukwudi, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan.
Chukwudi sọ pe irọ nla gbaa ni pe gomina Fubara ko gbe igbesẹ lati pa ina rogbodiyan to n rugbo bọ nipinlẹ ọhun ati o mọ nipa bi awọn ajigbara ṣe n dana sun ọpa epo bẹntiro nibẹ.
O ni lati igba ti Fubara ti gori alefa, gbogbo igbesẹ to n gbe ko ju ọna lati mu ọrọ aje ipinlẹ naa gberu ki ara le tu gbogbo mutumuwa.
Ninu iroyin kan naa, ẹgbẹ awọn ọmọ Niger Delta, iyẹn Pan Niger Delta Forum (PANDEF) ti bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Tinubu fun ikede ilu o fara rọ ni Rivers.
PANDEF juwe igbesẹ naa gẹgẹ bii igbogunti ijọba awarawa ni Naijiria ati fifi ọwọ ọla gba awọn eeyan agbegbe Niger Delta loju.















