Njẹ́ o ti gbọ́ nípa àwọn ìlú mẹ́fà yìí níbi tí òòrùn ò kìí wọ̀ rárá?

Ilu kan ni Norway to n ṣafihan bi oorun oru ṣe ri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Wakati mẹrinlelogun lo wa ninu ọjọ kọọkan fun gbogbo ẹda laye jakejado agbaye.

Ninu wakati mẹrinlelogun naa, wakati mejila pere ninu rẹ lo jẹ oju mọmọ, eyi tii ṣe asiko ti oorun ma n yọ, wakati yooku jẹ alẹ.

Ṣugbọn njẹ ẹ mọ pe awọn ilu kan wa ni aye yii to jẹ pe oorun kii wọ nibẹ, o kere tan, fun aadọrin ọjọ?

O ya yin lẹnu, abi? Bẹẹ lo ṣe ya awa naa lẹnu. Idi re e ti a fi ṣe akojọpọ awọn ilu mẹfa to wa lori oke eepẹ, nibi ti oorun kii ti i wọ bi awọn ilu yooku.

Norway

Ilu kan re e ni Norway nibi ti oorun o ki n wọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Norway ni ibi akọkọ ti oorun kii ti i wọ l'aye.

Norway to wa ni agbegbe ti wọn n pe ni Arctic Circle nilẹ Yuroopu, ni wọn tun ma n pe ni Land of Midnight sun. Orukọ yii to tumọ si Ilẹ Oorun Oru, ni wọn fun orilẹede naa nitori pe laarin oṣu Karun un ọdun si oṣu Keje, oorun kii wọ rara.

Eyi tumọ si pe kii si alẹ fun bi ọjọ mẹrindinlọgọrin.

Koda, niluu Svalbard lorilẹede Norway, lati ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin si ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ ọdun, ni oorun ma n jade lai wọ rara. Eyi tumọ si pe ko si alẹ tabi oru lawọn asiko yii.

2. Nunavut, Canada

Ilu keji ti oorun kii ti i wọ ni Nunavut, eyi to wa ni orilẹede Canada.

Nunavut ko jina rara si Arctic Circle, ni Ariwa Canada.

Ni ilu naa, fun bi oṣu meji ni oorun kii wọ lojoojumọ, amọ to ba di asiko otutu ti wọn n pe ni winter, fun ọgbọn ọjọ leralera ni wọn fi ma n wa ninu okunkun birimu.

3. Iceland

Orilẹede Iceland nilẹ Yuroopu ni awọn eeyan tun mọ si orilẹede kan ṣoṣo nibi ti ko ti si ẹ̀fọn.

Lasiko ooru ti wọn n pe ni Summer, oju mọmọ ni asiko ti awọn orilẹede yooku n pe ni alẹ tabi oru, ma n jẹ fun wọn ni Iceland.

To ba si ti di inu oṣu Kẹfa, oorun kii wọ rara.

Lati ri bi oorun ọganjọ oru naa ṣe l'agbara tabi mọlẹ to o ninu ẹwa rẹ, ilu Akureyri ati Grimsey Island to wa ni Arctic Circle, ni wọn ti ma n ri i wo daadaa.

4. Barrow, Alaska

Bi oorun oru ṣe ri ni Ọgba ẹranko Denali National Park, Wonder Lake Area,

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi oorun oru ṣe ri ni Ọgba ẹranko Denali National Park, Wonder Lake Area,

Orilẹede America ni ilu Barrow wa ni ipinlẹ Alaska.

Lati ipari oṣu KArun un si oṣu Keje ọdun, oorun kii wọ rararara ni ilu Barrow.

Amọ to ba tun di ibẹrẹ oṣu Kọkanla, titi di ọgbọn ọjọ lẹyin naa, oorun kii jade rara. Eyi ni wọn n pe ni 'Polar Night'.

Eyi tumọ si pe inu okunkun ni ilu naa ma n wa lasiko otutu.

5. Finland

Ilẹ Oorun Oru ni wọn n pe Finland. Agbegbe North Lapland re e , to n ṣe afihan bi oorun oru ṣe n ri nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilẹ Oorun Oru ni wọn n pe Finland. Agbegbe North Lapland re e , to n ṣe afihan bi oorun oru ṣe n ri nibẹ.

Iroyin sọ pe o to ẹgbẹrun kan adagun odo ati erekusu, to wa ni orilẹede Finland.

Ilẹ Yuroopu ni Finland wa.

Lasiko ooru ti wọn n pe ni summer, ọjọ bii mẹtalelaadọrin pere ni wọn fi n ri oorun laarin ọdun kan.

Lasiko yii, oorun ma n ran lai wọ rara.

Amọ to ba di asiko otutu, kii si oorun rara.

6. Sweden

Lati ayebaye ni oorun o ki ti n wọ ni Sweden. Ọdun 1838 ni wọn ya aworan yii niluu Maasoe, ibudokọ ọkọ oju omi ni North Cape, to n ṣafihan oorun oru.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lati ayebaye ni oorun o ki ti n wọ ni Sweden. Ọdun 1838 ni wọn ya aworan yii niluu Maasoe, ibudokọ ọkọ oju omi ni North Cape, to n ṣafihan oorun oru.

Ilu kẹfa ti a fẹ mẹnuba ni orilẹede Sweden, nibi ti oorun kii ti i wọ.

Ilẹ Yuroopu ni Sweden wa. Lati ibẹrẹ oṣu Karun un si ipari oṣu Kẹjọ, ọganjọ oru ni oorun ma n wọ ni Sweden.

To ba si tun ti di aago mẹrin idaji ni oorun yoo tun ti jade pade.

Iru asiko bayii ti oorun kii wọ le wa fun oṣu mẹfa gbako laarin ọdun kan nigba miran.