Ọkunrin ọmọ India tó kó ejò olóró mẹ́tàdínláàdọ́ta wọ ìlú kó sí gbaga àjọ aṣọ́bodè

Oríṣun àwòrán, Mumbai Customs-III/X
Bi ọka ba n lọ niwaju, ti paramọlẹ tẹle, ti ojola n wọ ruru bọ lẹyin, ta a ni jẹ ko ju wọn? Bayii ni Yoruba ma n wi, lati fihan bi ejo ṣe buru to, ti ko si si ẹni jẹ koju wọn.
Amọ ọrọ ejo ọhun lo ti ko ọkunrin si iyọnu bayii, lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ pe, o n gba ọna ti ko ba ofin mu, lati ṣe fayawọ ogunlọgọ awọn ejo afayafa ti iru wọn ko fi bẹẹ wọpọ.
Ninu awọn ejo naa la ti ri awọn to jẹ oloro, to si n gbiyanju lati ko wọn wọ orilẹede India.
Ọmọ orilẹede India hun, ni iroyin sọ pe lati Thailand lo ti n bọ, ti awọn oṣiṣẹ aṣọbode si da duro ni papapọ ọkọ ofurufu ilu Munbai, lọjọ Aiku.
Awọn alaṣẹ sọ pe oriṣiriṣi ejo, to fi mọ paramọlẹ oloro mẹtadinlọgọta, ni wọn ba ninu ẹru ọkunrin naa.
Wọn ti gba awọn ẹranko naa lọwọ rẹ ni ibamu pẹlu awọn ofin to ni i ṣe pẹlu ẹranko igbo.
Wọn ko ti i darukọ arinrinajo naa, amọ o ti w ani atimọle. Bakan naa ni oun paapaa ko ti i sọ ohunkohun lori bi wọn ṣe fin ofin mu u.
Ko lodi si ofin lati ko ẹranko wọ ilu, amọ awọn ilana kan wa

Oríṣun àwòrán, Mumbai Customs-III/X
Awọn oṣiṣẹ aṣọbode ti fi aworan awọn ejo naa to kun fun oriṣiriṣi awọ.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn ni apapọ ejo ti awọn gba lọwọ arinrinajo naa jẹ mejilelaadọta.
Ṣugbọn a ko ti i le sọ pato ibi to ti ri wọn ṣa jọ.
Lootọ ni ko lodi si ofin lati ko ẹranko wọle si India lati ilẹ okeere, amọ ofin to n daabo bo awọn ẹranko igbo tako kiko oriṣi awọn ẹranko kan lara eyi ti awọn ti iru wọn ti n tan lorilẹ aye tabi ti ijọba n daabo bo.
Bakan naa ni arinrinajo gbọdọ gba iwe aṣẹ ati ontẹ ijọba ko to o le ko ẹranko igbo wọle.
Igba akọkọ kọ niyii ti ọwọ tẹ awọn to n ṣe fayawọ ẹranko

Oríṣun àwòrán, Mumbai Customs-III/X
Eyi si kọ ni igba akọkọ ti awọn oṣiṣẹ aṣọbode n gbẹsẹ le awọn ẹranko ti ofin de, lọwọ awọn arinrinajo to n gbiyanju lati gba ọna ẹburu ko wọn wọle.
Ninu oṣu Kini, awọn alaṣẹ ni India mu ọkunrin ọmọ orilẹede Canada kan ni papakọ ọkọ ofurufu Delhi, fun pe o gbe ori ọọni sinu ẹru rẹ.
Ko ju oṣu kan lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọwọ tun tẹ arinrinajo kan to gbe Siamong Gibbon marun un. Awọn ẹranko naa to farajọ inaki, wọpọ ninu aginju ni Indonesia, Malaysia ati Thailand.
Bakan naa, ninu oṣu Kọkanla ọdun to kọja, awọn oṣiṣẹ aṣọbode mu arinrinajo meji to n bọ lati Bangkok fun pe wọn gbe ọmọ ijapa olowo iyebiye mejila dani.












