Iléeṣẹ́ ológun ṣèèṣì ju àdó olóró sáwọn aráàlú, àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní kí ìjọba ṣe ìwádìí

Oríṣun àwòrán, X/NIGERIAN AIR FORCE
Àjọ Amnesty International ti ké sí ìjọba Nàìjíríà láti ṣèwádìí àdó olóró àjọ iléeṣẹ́ ológun to ṣekúpa ogún èèyàn ní ìlú Maraya àti Wabi ní ìjọba ìbílẹ̀ Maru, ìpínlẹ̀ Zamfara.
Yàtọ̀ sí ogún èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn, ọ̀pọ̀ ló tún farapa níbi ìkọlù náà.
Àwọn aráàlú ní ìpínlẹ̀ náà sọ pé ogún èèyàn ló pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà fi ọkọ̀ òfurufú ju àdó olóró sí ìlú náà láti fi lásìkò tí wọ́n ń gbìyànjú láti kojú ìjà sáwọn agbébọn tó wà ṣe ìkọlù sí wọn.
Àwọn aráàlú náà ṣàlàyé pé ó lé ní àádọ́ta èèyàn táwọn agbébọn náà jí gbé ní oko wọn tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti pé ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun tó wá láti dóòlà wọn ṣèèṣì ju àdó olóró lu àwọn fijilanté tó ń kojú àwọn agbébọn náà
Àwọn èèyàn ìlú Mani ni ìjọba ìbílẹ̀ Maru sọ pé ọ̀sán gangan ni àwọn agbébọn gbé ọ̀kadà láti fi ṣe ìkọlù sí wọn nínú oko.
Wọ́n ní níṣe láwọn agbébọn náà da ìbọn bolẹ̀, tí wọ́n sì jí àwọn èèyàn gbé lọ.
Aráàlú kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ fún BBC News Hausa pé àwọn fẹ́ lọ ṣe ìrànwọ́ fáwọn tí agbébọn náà ń ṣèkọlù sí ni ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun dé, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn láti òkè, tó sì pa lára àwọn.
Ọkùnrin náà sọ pe" àwọn agbébọn náà kó àádọ́ta èèyàn àmọ́ bí ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun ṣe rí wa, wọ́n gbé ọkọ̀ òfurufú wọn wá sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn.
"Oníkálukú sá àsálà fún ẹ̀mí ara rẹ̀ kódà àwa tí a wà láyé gan orí ló kó wá yọ nítorí a dọ̀bálẹ̀ sílẹ̀.
"A dọ̀bálẹ̀ bí ẹni pé ìbọn ti bà wá ní, nígbà tí ọkọ̀ òfurufú náà lọ tán ni a dìde lọ fara pamọ́.
Ẹlòmíràn to bá BBC sọ̀rọ̀ rọ ìjọba láti ṣe ìrànwọ́ fáwọn nítorí àwọn agbébọn ti ṣèlérí pé àwọn máa padà wá.
Ó ní kí ìjọba kó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti wá dá ààbò bo àwọn ṣùgbọ́n nílò láti gbà pé àwọn ń ṣe àṣìṣe pa àwọn èèyàn àwọn nígbà míì, kí wọ́n ṣèwádìí kí wọ́n tó máa yìnbọn.
"A sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àmọ́ àwọn fijilanté wa ni àdó olóró wọn ṣekúpa."
Iléeṣẹ́ ológun kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Ní oṣù Kìíní, ọdún 2025, ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun ṣe àṣìṣe ṣekúpa èèyàn mẹ́rìndínlógún to fi mọ́ àwọn fijilanté àti àgbẹ̀ ní ìlú Tungar Kara ni ìpínlẹ̀ Zamfara tí wọ́n rò pé agbébọn ni wọ́n.
Ni oṣù Kejìlá ọdún 2024 ni wọ́n tún pa aráàlú mẹ́wàá ní Sokoto, tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà sì sọ pé àṣìṣe to kan àwọn aláìṣẹ̀ ni.















