Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò dùn mọ́ mi bí ààrẹ kò ṣe foyè dá àwọn tó jà fún ìsẹ̀jọba àwaarawa lámì ẹ̀yẹ tán
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ rí Kayode Fayemi ló sọ èyí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn èèyàn tí ààrẹ dá foyè dá lọ́lá ní àyájọ́ ìjọba àwaarawa
Fayemi ní ààrẹ kò rántí àwọn táwọn jọ ṣiṣẹ́ lórí rédíò Kudirat Abiola nílẹ̀ òkèèrè
Dele Momodu náà tún fèsì lórí báwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ pé ààrẹ kò rántí rẹ̀
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù Kẹfà ọdún 1993 ti mà á sọ fáráyé lọ́jọ́ iwájú
Ọgagun Hamza Al- Mustapha tó jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò Sani Abacha ló sọ bẹ́ẹ̀
Almustapha ni ọrọ June 12 le ju báwọn èèyàn ṣe lérò lọ
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Wò ó, jẹ́ ka sọ̀rọ̀ lórí àwọn àdó olóró tó wà ní ìkáwọ rẹ̀
Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ló sọ bẹ́ẹ̀ fún Iran lẹ́yìn tí Israel ṣèkọlù si lówùrọ́ òní
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Amẹ́ríkà ní awọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà
Trump ní láti oṣù méjì sẹ́yìn lòun ti fún Iran ní gbèdéke láti jíròrò
