Àwọn aláàrùn ọpọlọ wà nínú èèyàn mẹwa tó kú nílé alájà tó dà wó ní Ibadan

Ilé tí wọ́n tí ń wo alárùn ọpọlọ dawo Nibadan èèyàn mẹwa pàdánù ẹ̀mí, mẹ́jọ farapa.
Eeyan mẹwa lọ padanu ẹmi wọn nigbati eeyan mẹjọ miran farapa ninu ijamba ile alaja kan to dawo lagbegbe Jẹgẹdẹ ni agbegbe ijọba ibilẹ Ọna Ara nipinlẹ Oyo lẹkun iwọ oorun Gusu Naijiria.
Ile naa ni iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe o dawo ni nnkan bii aago meji owurọ oni.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC Yoruba, Adekunle Onifade ṣalaye wi pe lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ọhun ni awọn eeyan to ni arun ọpọlọ to ngba itọju nibẹ.

Ọgbẹni Onifade to jẹ kan lara awọn olugbe adugbo naa ṣalaye siwaju sii pe ori ko baba to n tọju awọn eeyan to ni arun ọpọlọ ni ile naa, ti pọ mọ si Baba Ire yọ ninu ijamba naa, ṣugbọn o farapa nigba ti ile naa dawo le lori.
Gẹgẹ bi alaye ti awọn olugbe miran ni adugbo naa sọ, ile naa ti n sọko tipẹ, bẹẹni ni wọn ni wiwo ile naa loju fihan pe o ti yẹ fun atunṣe tipẹtipẹ.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹ?
Ọga agba ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Ọyọ, Ẹniọwọ Akinyẹmi Akinyinka sọ pe nnkan bii agogo meji oru ni awọn gba ipe pe ile naa da wo.
O fi kun un pe oku eeyan mẹwaa ni wọn gbe jade labẹ awoku ile naa nigba ti wọn bẹrẹ iṣẹ idoola ẹmi nibẹ, awọn miran si tun farapa
Ki ni awọn alaṣẹ ijọba ni ipinlẹ Ọyọ sọ?

Kọmisọna fun ọrọ ile ati ilẹ nipinlẹ Oyo, William Akin-Funmilayọ ti ṣe abẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Ninu ọrọ to sọ lasiko abẹwo rẹ si ibi iṣẹlẹ naa, Kọmisọna William Akin-Funmilayọ woye pe, aini akakun ati aìgbọran awọn olugbe ile naa lo faa iṣẹlẹ ọhun, nitori wi pe kedere lo han wi pe o ti rẹ ile naa.
O ni ijọba Ipinlẹ Oyo yoo gbe igbese lati dẹkun irufẹ ijamba yii nipa ṣiṣe ayẹwo gbogbo to yẹ si awọn ile ni ipinlẹ naa lati mọ boya okun n bẹ fun wọn lati duro tabi o ti rẹ wọn sara.















