Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí àwọn ọmọ oògùn Chad bá kúrò lára ìkọ́ ológun ìwọ̀ oòrùn Afrika?

Aworan awọn ikọ ologun Chatd

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Armand Mouko Boudombo, Isidore Kouwonou
    • Role, Journalists- BBC News
    • Reporting from, Dakar
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ikọ agbebọn ati awọn ẹgbẹ ologun miiran nigbagbogbo ma lo agbegbe Lake Chad gẹgẹ bi ibudo lati kọlu awọn orilẹ-ede bii - Nigeria, Niger, Chad, ati Cameroon - ṣugbọn idunkoko ti Aare Chad dun lati yọ orilẹede Chad kuro ni ikọ ologun ti ọdun mẹwa le ni ipa nla ti o le ṣe.

Lẹyin ọdun mẹwaa iṣẹ ologun apapọ ti orilẹede Cameroon, Chad, Niger ati Nigeria ti n koju ija lati kọlu igbesunami ni Iwọ-oorun ati aarin gbogbo Afrika.

Igbesẹ yii le fa ifasẹyin. Iyẹn ni ti Aarẹ Chad Mahamat Idris Deby ba mu ikọ ologun Chad kuro ikọ ologun iwọ oorun.

O le ni ogoji ọmọ ogun Chad to padanu ẹmi wọn sọwọ ikọ agbebọn Boko Haram lo fa ti Aarẹ Deby fi ṣabẹwo si ibudo ni Barkaram, ni agbegbe Lake Chad. Nibẹ, o kede iṣẹ ologun kan lati tọpa awọn agbebọn naa.

Agbegbe Lake Chad ni agbegbe to so Cameroon, Chad, Niger ati Nigeria - eyiti gbogbo wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ (MNJTF) lati ọdun 2015, ti n wa lati pa awọn ẹgbẹ ologun to n ṣiṣẹ ni agbegbe naa.

Lẹyin ibẹwo Deby si awọn ologun, Aarẹ Chad fi atẹjade kan sita, nibiti o ti sọ pe Ẹgbẹ apapọ Agbofinro ko si iṣọkan laarin awọn ọmọ ogun ti awọn orilẹ-ede naa ti n wọn koju Boko Haram. Nitori naa, orilẹ-ede naa n gbero yiyọ kuro ninu ẹgbẹ naa lẹyin ọdun mẹwaa.

"Igbiyanju Chad lati se iyọkuro kuro ninu égbẹ ologun yii le fa ọpọ ifasẹyin fun ẹgbẹ naa," Ojogbon Oumar Ba ni Ile-iṣẹ ti diplomatic ati awọn ẹkọ ilana ni Paris, France sọ fun BBC.

Awọn ifasẹyin wo lo le waye?

Ikọ ologun yii, eyi ti olu ile-iṣẹ rẹ wa ni Chad, ni awọn ọmọ ogun toto ẹgbẹrun mẹwaa ni ọdun 2022, ti wọn wa lati awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ, gẹgẹ bii ajọ MNJTF ṣa ṣalaye. Ni ọdun 2018, nigba ti ẹgbẹ-ogun naa ni awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun mẹjọ, Chad ṣe afikun awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun mẹta si i, ẹlẹẹkeji ti o tobi julọ lẹyin Naijiria, ti o fi ọmọ ogun to le ni ẹgbẹrun mẹta ransẹ. Ilu Cameroon ni awọn ọmọ ogun 2,250, Niger ati Benin ni awọn ọmọ ogun 200 ati 150 ni, gẹgẹ bi atẹjade ti ile-iwe agbaye ti awọn ologun aabo ni Ilu Cameroon.

Iyọkuro Chad le jẹ ki ikọ aabo naa padanu orilẹede ẹlẹẹkeji rẹ to pese ọpọ ọmọ ogun ni akoko ti eto aabo si mẹhẹ.

Ceidik Abba, oluwadi aabo kan, sọ fun BBC pe "eyikeyi yiyọ kuro yoo jẹ ifasẹyin nla fun ikọ naa", paapaa lọwọ ti Chad n koju igbesunami.

Abba, ẹni ti o kọ iwe kan lori oye rẹ nipa Boko Haram, 'Pour comprendre Boko Haram', sọ pe loni, Boko Haram kii ṣe ọta orilẹ-ede (fun orilẹ-ede kọọkan), ṣugbọn fun gbogbo agbegbe. Ati pe ti ija Boko Haram ba fẹ munadoko, wọn gbọdọ ṣe nipasẹ fifi fọwọsowọpọ. Laisi rẹ, ikọlu lati awọn ẹgbẹ oriṣiriṣi yoo lọ kọja awọn ibi aabo ni awọn orilẹ-ede oriṣiriṣi lati ibiti wọn yoo ṣe ifilọlẹ awọn ikọlu.

"Mo nireti pe ohun gbogbo yoo ṣee ṣe lati yago fun eyi, nitori Chad mu ọpọlọpọ iririwa, ati pe iyiyọ kuro yoo tun tumọ si ipada si ẹyin," o sọ.

Idi ti ikọ ologun naa fi n tiraka

Aworan olor ijọba Chad

Oríṣun àwòrán, Screenshot Presidency of the Republic Chad

Ni ọdun 2019,Aarẹ Deby to ti di oloogbe - baba ti Aarẹ Chad lọwọ yii – koroju si bi awọn orilẹede kan se kuna lati pese awọn ọmọ ogun lati darapọ mọ ikọ ologun naa. Iroyin sọ pe oloogbe naa ni awọn ologun ti Chad lo n ṣe ọpọlọpọ iṣẹ ni agbegbe Lake Chad, lakoko ti awọn orilẹ-ede miiran ti dojukọ awọn iṣẹ mii.

Ṣugbọn agbegbe Lake Chad si jẹ aaye fun awọn ẹgbẹ agbebón lati kọlu awọn orilẹ-ede laarin agbegbe naa.

Awọn ẹdun ọkan naa ni ọmọ rẹ ti jogun, ti o jẹ aarẹ lọwọlọwọ fun Chad, o sọ pe awọn orilẹ-ede yooku ti o yẹ ki o jẹ alabaṣepọ ninu ogun naa ko ṣe to.

“Awọn orilẹ-ede yii kọ lati ṣe ipa ti wọn ,” Abba, oniwadi aabo.

O tun sọ pe ẹgbẹ ologun apapọ ko ni ohun irinsẹ toto to to. Awọn baalu kekere lo wa lati gbe awọn ọmọ ogun to ba farapa ati gbe awọn ogun lọ ayika..

"Bawo ni a ṣe le rii daju pe gbogbo awọn orilẹ-ede ni sde ohun to yẹ ki wọn ṣe ki wọn si pese ohun to tọ?" Abba beere.