Aráàlú da ẹrẹ̀fọ̀ sí Ọba àti Olorì lára níbi ìfẹ̀hónúhàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé

Àkọlé fídíò, Aworan awọn oluwọde to n lẹ nnkan mọ Ọba Spain
    • Author, Emily Atkinson
    • Role, BBC News
    • Author, Mark Lowen
    • Role, Europe correspondent
    • Reporting from, Valencia
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn oluwọde lẹkun Valencia lorilẹede Spain da ẹrẹfọ si Ọba orilẹede Spain, Felipe VI ati Olori rẹ, Letizia, lara lasiko ti ori ade naa ṣabẹwo sawọn agbegbe ti omiyale ti ṣẹlẹ lẹkun naa.

Ariwo ''apayan'' ati ''alailojuti'' lawọn eeyan n ke bi ọba yii ati olori rẹ ṣe n rin kọja niluu Paiporta.

Awọn araalu to n binu yii tun ju nnkan si Olootu ijọba Spain, Pedro Sánchez, bakan naa, amọ, o tete ba ẹsẹ rẹ sọrọ.

O le ni igba eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ ẹkun omi to waye naa, eleyii to ṣẹlẹ fun igba akọkọ lọpọlọpọ ọdun lorilẹede Spain.

Inu n bi awọn araalu wi pe ijọba o ṣe ikilo to to fawọn eeyan ṣaaju iṣẹlẹ ẹkun omi naa.

Bakan naa lawọn eeyan tun n sọ pe ijọba ko ṣe iranwọ to to fawọn ti ẹkun omi ṣe ipalara fun.

Fidio kan ṣafihan bi Ọba Felipe VI ti n rin lọ kawọn ẹṣọ rẹ atawọn ọlọpaa to bẹrẹ si ni maa ṣe faakaja pẹlu awọn oluwọde ti wọn n pariwo mọ ori ade ọhun.

Ọba Felipe n ba ẹnikan sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn araalu to n binu rọgba yi Ọba Felipe ka nibi to n ti n rin loju popo

Awọn eeyan to n fẹhonuhan fi ibinu yi Ọba Felipe ka, wọn si bẹrẹ si ni maa lẹ ẹ ni amọ atawọn nnkan mii.

Amọ, Kabiyesi naa si gbiyanju lati ba awọn kan sọrọ ninu awọn oluwọde ọhun.

Awọn fọto to jade sita ṣafihan bi amọ ṣe wa loju ati lara aṣọ Ọba Felipe ati Olori Letiza to fi mọ awọn iṣọmọgbe wọn to mu aburada lọwọ.

Àkọlé fídíò, Olori Letizia bu sẹkun lasiko abẹwo rẹ sibi ti ẹkun omi ti ṣẹlẹ ni Valencia

Olootu ijọba Sánchez ati olori ijọba ẹkun Valencia, Calos Mazón ti wọn darapọ mọ ori ade naa tete fẹsẹ fẹẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin lorilẹede Spain sọ pe awọn eeyan n lẹ nnkan mọ Olootu ijọba Sánchez, nigba ti fidio ti BBC ri ṣafihan bawọn eeyan kan ṣe n lẹ oko mọ ọkọ ti Ọgbẹni Sanchez wa ninu rẹ.

Lẹyin ti olootu ijọba naa tilẹ tan ni wọn bẹrẹ si ni beere wi pe - ''nibo ni Sanchez wa/''

Ọdọkunrin kan, Pau, ọmọ ọdun mẹrindinlogun sọ fun BBC pẹlu omije loju pe ijọba ko na an ni araalu.

Pau ni awọn eeyan n ku nigba ti ijọba ko ṣe nnkan kan sii.

Obinrin mi-in sọ pe ''wọn fi wa silẹ pe ki a ku, a si ti padanu gbogbo nnkan wa.''

Ọba Spain gbero lati ṣabẹwo si Chiva to jẹ ilu mii lẹkun Valencia ṣugbọn ori ade naa ko ni le lọ sibẹ mọ.

Ọba Felipe pada sọ pe ifẹhonuhan awọn araalu ye oun yeke yeke ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ.

Aworan obinrin to n pariwo lara awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ti le ni ọgọta eeyan to ti padanu ẹmi wọn niluu Paiporta

Adari ijọba ilu Paiporta, Maribel Albalat sọ fun BBC pe ihuwasi awọn eeyan si Ọba Felipe ati Olootu ijọba Sanchez lasiko abẹwo wọn jẹ iyalẹnu foun.

Ẹwẹ, omọ ile igbimọ aṣofin kan lẹkun Valencia, Juan Bordera, ṣapejuwe abẹwo Ọba Felipe gẹgẹ bi igbesẹ to buru jai.

Bordera ni awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Spain kii gbọ ikilọ.

Lọjọ Satide to lọ ni Olootu ijọba, Sanchez ran awọn ẹṣọ eleto abo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa lọ si ẹkun naa.

Ọjọ Iṣẹgun ni ẹkun omi naa bẹrẹ lẹyin ojo arọọrọda kan to rọ.

Ẹkun omi yii lo wo awọn afara kan lulẹ ti o si jẹ ki ẹrẹfọ bo awọn ilu mọlẹ.

Ọpọ ilu ko ni anfaani lati lo ina mọnamọna atawọn nkan amayedẹrun mii mọ, nigba tawọn ilu mii ko si ri ounjẹ jẹ tabi ri omi mu mọ.

Aworan obinrin to n rin ninu ẹrẹfọ lẹyin ẹkun ọmi ni Spain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan obinrin to n rin ninu ẹrẹfọ lẹyin ẹkun ọmi ni Spain

Awọn to ti ku nibi ẹkun omi ni Spain ti pe 217 lọjọ Aiku to kọja, nigba ti ọpọ eeyan si di awati.

Ẹkun omi naa ṣe akoba nla fun ọpọ ilu papaa julọ lagbegbe Valencia.

O kere tan eeyan mejilelọgọta lo ti padanu ẹmi wọn niluu Paiporta ti Ọba Felipe ṣabẹwo si.

Ajọ AMEMET to n ri si ọrọ oju ọjọ lorilẹede Spain sọrọ lọjọ Aiku to kọja lori ojo nla ti yoo rọ lawọn agbegbe kan ni Valencia bii ilu Alzira, Cullera ati Gandia.

Get in touch

Are you in the Valencia region? If it's safe to do so, please share your experiences.