Àwọn ohun méje tí Trump ṣèlérí láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, James FitzGerald
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Donald Trump ti n mura silẹ lati pada sile ijọba ilẹ Amẹrika, White House, lẹyin awọn ileri to ti ṣẹ ṣaaju faraalu.
Nigba to n sọrọ lori aṣeyọri rẹ ninu ibo Aarẹ, o ni afojusun oun ni lati mu gbogbo awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo bo ṣẹ fun awọn eeyan Amẹrika.
Oniruru ileri ni Trump ṣe faraalu lasiko ipolongo ibo rẹ, awọn kan fẹran awọn ileri naa, bẹẹ lawọn mii bu ẹnu atẹ lu diẹ lara awọn ohun to ni oun yoo ṣe.
Iwọnyii ni awọn ohun meje ti Trump ṣeleri pe oun yoo ṣe ti oun ba pada de ipo Aarẹ
1) Lile awọn alejo ti ko ni iwe igbelu pada si orilẹede wọn
Lasiko ipolongo ibo, Trump ṣeleri pe oun loun maa le awọn atọhunriwa ti ko ni iwe igbelu pada silẹ wọn ju ninu itan ilẹ naa.
O tun ṣeleri lati pari odi ti wọn n kọ laarin orilẹede Amẹrika ati Mexico ti wọn bẹrẹ ni saa rẹ akọkọ.
2) Mimu adinku ba awọn owo ori kan
Trump ṣeleri lati fopin si ọwọngogo to gbode laasiko jọba Biden, bẹẹ lo tun ṣeleri lati mu adinku ba awọn owo ori kan.
3) Idariji awọn oluwọde ‘Capitol riot'
Trump sọ pe oun yoo tu awọn kan silẹ lara awọn ti wọn ṣedajọ fun lori pe wọn lọwọ ninu iwọde Capitol riot to waye lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2021.
Iwadsii ni awọn ololufẹ Trump lo ṣe iwọde naa latari pe inu wọn ko dun si bi Joe Biden ṣe bori idibo lọdun 2020.
Iroyin ni ọpọ eeyan lo ku latari iwọde naa, eyii ti wọn sọ pe Trump gan lo ṣokunfa rẹ.
Amọ Trump sọ pe pupọ ninu awọ eeyan ọhun ni wọn fi si ẹwọn lai mọwọ-mẹsẹ ninu iṣẹlẹ naa.
4) Gbigba iṣẹ lọwọ amofin Jack Smith
Trump ti ṣeleri lati gba iṣe lọwọ Jack Smith laarin iṣẹju meji pere ti oun ba pada gori alefa.
Ṣaaju ni amofin Jack Smith yii ti kọkọ fẹsun kan Trump nile ẹjọ pe o fẹ doju ijọba Biden bolẹ lọdun 2020.
Amọ Trump sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti ọkunrin amofin naa fi kan oun.
5) Ileri lati fopin si ogun Ukraine
Trump ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Joe Biden latari ẹgbẹlẹgbẹ owo gọbọi to fi n ranṣẹ si Ukraine gẹgẹ bii atilẹyin ninu ogun rẹ pẹlu Russia.
Trump ko fẹ ki ijọba Amẹrika maa da si ọrọ ogun ilẹ okeere rara.
6) Ọrọ oyun ṣiṣẹ
Lodi si ifẹ inu awọn alatilẹyin rẹ kan, trump sọ pe oun yoo fun awọn ipinlẹ ni ore ọfẹ lati yan boya wọn faramọ oyun ṣiṣẹ tabi bẹẹ kọ, amọ ko sọ pe oun yoo gbẹsẹle ofin to gbe lẹyin oyun ṣiṣẹ.
7) Mimu adinku ba awọn ofin to nii ṣe pẹlu ayipada oju ọjọ
Lọna ati ṣeranlọwọ fun awọn ileeṣẹ to n ṣe ọkọ l’Amẹrika, Trump ni oun yoo mu adinku ba awọn ofin to nii ṣe pẹlu ayipada oju ọjọ to wa nilẹ tẹlẹ.












