Wo ẹ̀rọ tó ń sẹ́ omi ṣe ń mú àyípadà bá àwọn agbègbè kan l'Africa

Aworan ọmọde to fẹ mu omi

Oríṣun àwòrán, UpEnergy

    • Author, Soo Min Kim
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ní Kawempe, Uganda, Nicholas Mukiibi maa ronu nipa omi lojoojumọ.

Riri omi mimu to mọ jẹ ipenija nla, ti ọpọ awọn omi to mọ lon wa ninu igo ti wọn si wọn tabi ko wọn gbe omi kana pẹlu lilo eedu — ilana lati se lo gba ọpọ akoko.

“Apo eedu kan lo jẹ 80,000 sí 90,000 shilling Ugandan [$21-$24],” ni Nicholas sọ. "O soro lati ri ma ra awọn eedu yii."

Ni ọdun 2021, nnkan yipada fun Nicholas nigbati o pade ẹrọ to n fọ omi mọ ni ile ti ọrẹ rẹ.

Ẹrọ naa wa lati ileeṣẹ kan ti a pe ni UpEnergy.

“Mo lo omi lati inu ẹrọ yii ni ọdọ ọrẹ mi fun ọsẹ meji, ti n ko si se aisan, ti mo si ni lati ra ọkan fun awọn mọlẹbi mi,” Nicholas sọ.

Ẹrọ ifọ omi UpEnergy lo jẹ 50,000 shillings Ugandan [$13.6].

Nicholas ti n lo ẹrọ yii fun ọdun mẹta. “O jẹ ki n fi owo pamọ, ati pe n ko ronu nipa aisan mọ ati pe omi naa ko ni ayipada lẹnu.

Nicholas ba awọn ọrẹ rẹ marun un sọrọ ninu agbegbe lati gba ẹrọ omi ti o da lori iriri rẹ. "O jẹ nkan kekere, ṣugbọn o ṣe iyatọ nla ninu igbesi aye wa," Nicholas sọ.

Aworan tanki Omi

Oríṣun àwòrán, UpEnergy

Ẹrọ omi UpEnergy kọja ilegbe. Ni awọn ileẹkọ kọja lọ si Malawi, Zambia ati Tanzania, nibiti awọn arun inu omi ti wọpọ nigbakan laarin awọn ọmọ ileẹkọ, UpEnergy ti gbe ẹrọ sibẹ. Awọn ilana yiin tọju omi, to si n yọ idọti kuro, eyi to fun awọn akẹkọọ ni anfani lati mu omi to mọ lojoojumọ. Ọfẹ ni wọn gbe awọn ẹrọ naa kalẹ, ọkan si wa pẹlu idaniloju ọdun marun un.

“Mo maa n ṣaisan nigbagbogbo latara mimu omi idoti lati inu iho ti o wa nitosi ile ẹkọ naa. “Emi ko ni aisan igbẹ gbuuru mọ lati inu omi iho, ati pe emi ko ni lati pa ile ẹkọ jẹ nitori rẹ.” Elestina Tembo, ọmọ ile ẹkọ kan ni Ile-iwe alakọbẹrẹ Mchinji Mission ni Malawi lo sọ bẹẹ.

“Iyatọ ti wa pẹlu awọn ọmọ ile ẹkọ to n wa to si ṣe pataki,” Zacharia Phiri, olukọ ile-iwe alakọbẹrẹ Mchinji Mission ni Malawi sọ. "Awọn ọmọde ati awọn olukọ ni wọn wa ile ẹkọ deede."

Aworan awọn eeyan to n mu omi

Oríṣun àwòrán, UpEnergy

"O ko le gbe ẹrọ kan wa ki o wa fi silẹ lọ," Lafelle Shiomitsu, Oludari Orilẹ-ede fun UpEnergy ni Uganda sọ. "A ṣiṣẹ ni pẹkipẹki pẹlu awọn agbegbe lati rii daju pe awọn ojutu n se nnkan ti a fẹ."

Eyi ni yiyẹ awọn ẹrọ naa wo lorekore, itọju ati ẹkọ mimọ lati ṣe atilẹyin fun lilo ẹrọ naa fun igba pipẹ .

Gẹgẹ bi UpEnergy ṣe sọ, ẹrọ yii n pese omi mimọ fun eeyan to le ni 90,000, ti awọn ẹrọ si ti jẹ ohun ina fun ile gbe toto 100,000.

"Ẹrọ UpEnergy ko peṣe iranlọwọ fun awọn akẹkọọ 1,500 nikan ni ile-ẹkọ ṣugbọn awọn eeyan ti o wa ni abule,” Zacharia sọ. “Gbogbo wa ni a jẹ anfaani omi to mọ yii,ti a si ni ireti pe a o ni tanka to tobi lati ti yoo jẹ ki ọpọ wa tun jẹ anfani si.

community.”