Ṣé Ọba lé gba olórí tó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ padà sí ààfin ní ilẹ̀ Yorùbá?

Aworan awọn olori ọba niluu London

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Afolabi Akinlabi
    • Role, Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni aye atijọ, ohun iwuri lo jẹ fun ọpọ obinrin ti wọn ba di iyawo ọba alade ilu, ti awọn araalu si ma bu ọwọ nla fun wọn.

Bi o ti lẹ jẹ pe aṣa ko fi aye gba awọn olori ọba lati kọ ọba silẹ ti wọn si ma fi ori ti igbeyawo.

Ọpọ nnkan to jẹ ti aṣa lo dirọ mọ pe ki obinrin kọ ọba alade silẹ, ko si lọ fẹ ọkunrin mii gẹgẹ bii ọkọ.

Ṣugbọn ode oni, ọpọ ori ade ni awọn olori wọn ti kuro ni aafin lori idi si meji.

Ibeere ti a n bẹrẹ ni pe n jẹ aṣa fi aye silẹ fun oba alade lati tẹwọgba olori to kọ silẹ pada si aafin.

BBC Yoruba kan si awọn to ni imọ kikun nipa aṣa ati iṣe Yoruba lori ọrọ naa, ti wọn si tan imọlẹ si.

Ki lawọn ohun to le gbe olori pada si aafin lẹyin to ba ti kọ ọba tabi ti ọba ba ti kọ ọ?

Aworan olorI Oba

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Ogboni Igba Iwasẹ, Adeyinka Arifanlajogun ninu alaye rẹ ni ọba le gba iru obinrin naa pada to ba jẹ pe ko ti jẹ ohun eewọ tabi ba ọkunrin mi ni ajọsepọ.

“Obinrin to ko kuro ni aafin ọba, ọkunrin ko gbọdọ gun ori rẹ mọ yatọ si ọba to fẹ si ile.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Ti Obinrin ba kuro ni aafin Ooni sugbọn to pada ronu, to si piwada, niwọngba ti ko ba ti ba ọkunrin mi lopọ, ọba alade le gba pada.

Baba Yemi Elebubon naa ba BBC Yoruba sọrọ lori boya aṣa fi aye silẹ fun obinrin to ba kọ ọba silẹ lati pada si aafin.

Elebubon ni eyi lo da iru ẹsẹ ti obinrin ba ṣẹ to fi di pe o kuro ni aafin.

“Ẹṣẹ obinrin tabi olori lo yoo sọ boya o le pada si aafin lẹyin to ba kọ ọba silẹ. To ba ti lọ ni aafin, o ti lọ niyen sugbọn iru ẹsẹ to ṣe ni yoo sọ boya ọba le gba pada.

“Bi ko ki n ṣe ọba gan, obinrin to ba n lọ to n bọ, bi ko ba pa ọkọ yoo pa ara rẹ. Ti ẹsẹ ko ba wuwo, ọba le gbe pada.”

Afolashade Adeyemi, Ọmọọba Alaafin ti ilu Oyo to waje, Oba Lamidi Adeyemi ni pupọ awọn olori to kọ Alaafin silẹ ni wọn gba laaye lati pada si aafin mọ.

Ọmọọba Adeyemi ni laye atijọ awọn olori ki n kọ ọba alade silẹ, ti wọn si ma foriti gbogbo ohun ti wọn la kọja ni ile ọkọ.

“Nigba ti Baba mi wa lay, a ni awọn olori ti wọn kuro ni aafin, ti wọn si gba wọn pada sugbọn wọn ki ni aafin lati pada wa gbe ninu aafin mọ.

“Ọba ko ki n kọ iyawo silẹ sugbọn ti wọn kọ ọba silẹ, wọn ko ki n pada si aafin, ti baba yoo si ra aṣọ fun wọn lọtọ.

“O ni awọn kan ti kabiyesi ko gba pada nigba ti wọn wa bẹbẹ sugbọn ọba n tọju ọmọ. Ni aye atijọ, wọn ko ki n gbe ọmọ kuro ni aafin.

“Ti o ba fi ọwọ ara rẹ ko ẹru rẹ kuro ni aafin Adeyemi, o le pada mọ si aafin sugbọn wọn da aṣe ru ni aye ode yii.”

Se olori to ba kọ ọba silẹ le fẹ ọkunrin mii?

Gẹgẹ bii alaye awọn amoye nipa aṣa Yoruba ṣe ṣalaye ọrọ naa, ọpọ awọn olori to ba kọ ọba silẹ ni wọn ko gbọdọ fẹ ọkunrin mii lai ṣe pe wọn se awọn etutu kan ti yoo fun anfani lati ni ibujoko ayo ni ile ọkunrin mii.

Ọba Ogboni Igba Iwasẹ, Adeyinka Arifanlajogun ti obinrin to kọ ọba silẹ ba ni pe oun ko pada si ile ọkọ, o di dandan pe ki wọn tu eekana lẹyin ọọrun rẹ.

“O di dandan pe ki wọn se awọn etutu kan fun obinrin bẹ to ba fẹ ni alaafia ni ile ọkọ mii to n lọ.”

Baba Yemi Elebubon ni yatọ si pe obinrin kọ ọba silẹ, ti ọba ba waja, ti obinrin naa si nifẹ lati fẹ ọkunrin mii, obinrin ati ọkọ to nifẹ si gbọdọ ṣe etutu ki wọn le mu ọwọ ọba kuro lara obinrin naa.

Ọpọlọpọ aṣa, eewọ ati igbagbọ lo wa lori ọrọ awọn olori ati ọba ni ilẹ Yoruba. Lara rẹ ni pe iyawo ọba, iyẹn olori ko gbọdọ fẹ ọkunrin miran mọ koda ki ọba naa ti waja.

Kabiyesi Ọba Ọọni ilẹ Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ẹniitan funrarẹ sọrọ lori eyi nigba diẹ sẹyin pe bi o ba wu olori to ba kọ ọba silẹ, o le fẹ ẹlomiran niwọn igba ti wọn ba ti ṣe gbogbo etutu ati ilana to ba yẹ lati tu u silẹ kuro ninu majẹmu to wọ nigba to fẹ Ọba.

Ninu ọrọ to gba ẹnu agbẹnusọ rẹ, Oloye Moses Ọlafare sọ Ọọni ile Ifẹ ni, “ ko si idi fun obinrin lati wa ninu ide ayeraye ṣugbọn awọn etutu gbogbo to yẹ nilati wa ni ṣiṣe lati dena awọn ajalu buruku”.

Eekan ninu ọrọ aṣa ati iṣe yoruba, Biṣọọbu agba Ayọ Ladigbolu ṣalaye lẹyin ti Alaafin Adeyẹmi kẹta gbesẹ pe awọn olori alaafin le fẹ ọkọ miran; amọṣa o ni ọjọ ori ati bibu ọwọ fun ara ẹni le mu ki wọn o se ara wọn kuro ninu ṣiṣe bẹẹ.

“O le jẹ eewọ bi eeyan ba wo awọn ohun ikọkọ ati eewọ gbogbo to rọ mọ igbeyawo awọn oriade.”

Ọkan lara awọn eekan ọbalaye ni ipinlẹ Ogun, Ọba Akintunde Akinyẹmi pẹlu sọ ọ nigba kan sẹyin peolori to ba la awọn ilana iṣẹmbaye kọja nigba to n ṣe igbeyawo pẹlu ọba ko le fẹ ọkunrin miran mọ. O fi kun un pe ẹnikẹni to ba da aya de iru obinrin bẹẹ ti ru igi oyin ayeraye.