O ṣeéṣe kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ fídíò ìbálòpọ̀ tó lu jáde níiṣe pẹ̀lú ipò òṣèlú àti agbára dídù ní Equatorial Guinea? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Baltasar Ebang Engonga / Facebook
- Author, Ines Silva & Damian Zane
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ohun ti gbogbo eeyan n wo gẹgẹ bi fidio Ibalopọ le pada jẹ ohun ti yoo sọ ẹni ti yoo di aarẹ to kan lorilẹede Equatorial Guinea.
Ni bii ọsẹ meji bayii ni fidio ti a gbọ pe o le ni irinwo ti lu jade eyi to n ṣafihan ni ọkunrin kan to jẹ ọga lẹnu iṣẹ ijọba ti n ni Ibalopọ pẹlu oriṣiiriṣii obinrin ni ọọfisi at'awọn ibomiran.
Awọn fidio naa ti lu ori itakun ayelujara pa eyi to jẹ iyalẹnu fáwọn eeyan orilẹede Equatorial Guinea ati gbogbo awọn eeyan orilẹede mii ti wọn ri awọn fidio naa.
Ọpọ awọn obinrin to wa ninu awọn fidio naa lo jẹ iyawo ati Ibatan awọn to jẹ abenugan ninu ijọba to wa lode ni Equatorial Guinea.
O dabi ẹni pe ọpọ ninu awọn obinrin yii lo mọ pe Ọgbẹni Baltasar Ebang Engonga tawọn eeyan tun mọ si Bello tori o rẹwa l'ọkunrin n ṣe fidio ibalopọ ti wọn jọ ni.
Amọ, o ṣoro lati fidi eyi mulẹ tori orilẹede Equatorial Guinea ko fún awọn akọroyin lati ṣiṣẹ wọn pẹlu ominira daadaa.
Amọ, nnkan kan t'awọn eeyan kan sọ ni pe fídíò to jade yii jẹ ọna lati tabuku ọkunrin ti ọrọ da lori.
Ọgbẹni Engonga to jẹ ibatan Aarẹ Teodoro Obiang Nguema wa lara awọn to le rọpo aarẹ orilẹede naa.
Obiang ni aarẹ to ti pẹ lori oye julọ lagbaaye lẹyin to ti wa nipo lati ọdun 1979.
Diẹ lara awọn eeyan orilẹede naa lo jẹ ọlọrọ, amọ, pupọ ninu awọn eeyan Equatorial Guinea ti wọn ko ju 1.7m lọ ni iṣẹ ati osi n ba a finra.
Ọpọ lo ti koro oju si iha ti Aarẹ Obiang ẹni ọdun mejilelọgọrin si ẹtọ ọmọniyan, to fi mọ pipa eeyan ni ipakupa ati ifiyajeni gẹgẹ ijọba Amẹrika ṣe sọ.
Iroyin tun ti jade nipa bi ọkan lara awọn ọmọkùnrin Aarẹ Obiang eyi to ti di igbakeji aare bayii ṣe na owo ni ina kuna debi pe o fi $275,000 ra ibọwọ ti agbaojẹ olorin takasufe n ni Michael Jackson lo nigba aye rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe eto idibo n waye, ko fi bẹẹ si alatako fun ijọba Aarẹ Obiang pẹlu bi ijọba ṣe n ju awọn ajafẹtọọ si ẹwọn nigba t'awọn mii n fi ilu silẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọgbẹni Engonga jẹ adari ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ to fi mọ awọn to n ji owo ko lọ soke okun.
Ṣugbọn o ṣẹlẹ wi pe wọn n ṣewadii Engonga fun ra rẹ lori ẹsun jibiti.
Engonga ko tii sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Wọn gbe Ọgbẹni Engonga lọ ọgbà ẹwọn Black Beach to wa ni Malabi tii ṣe olu ilu Equatorial Guinea.
Wọn gba foonu ati ẹrọ kọmputa rẹ, lẹyin ọjọ meloo kan si akoko yii ni fidio Ibalopọ rẹ pẹlu oriṣiiriṣii obinrin lu ori ayelujara pa.
Lori itakun agbọrọkaye akoroyin kan, Diario Rombe, ni BBC ti kọkọ gbọ nipa awọn fidio naa lọjọ kejidinlogbon oṣu Kẹwaa to kọja.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọpọ eeyan lo mu fidio lori itakun ayelujara.
Bayii l'awọn eeyan bẹrẹ si ni maa gbe fidio naa kaakiri lori foonu wọn.
Kiakia l'awọn eeyan ti da Ọgbẹni Engonga mọ pẹlu ọpọ awọn obinrin to ba ni Ibalopọ mọ.
Ijọba kọkọ kọ eti ikun si ohun to n lọ ki igbakeji aarẹ, Teodoro Obiang Mangue to pàṣẹ fawọn ileeṣẹ eto ibaraẹnisọrọ lati dẹkun pipin fidio naa ka.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti rọ awọn obinrin to wa ninu fidio naa lati wa pe Ọgbẹni Engonga lẹjọ pe awọn o ni adehun pẹlu Ọgbẹni wi pe yoo pin fidio ibalopọ awọn atiẹ lọjọ iwaju.
Obinrin kan ti sọ pe oun maa pe Ogbeni Engonga lẹjọ.
Yatọ si pe Engonga jẹ ibatan Aarẹ Obiang, o tun jẹ ọmọ Ọgbẹni Baltasar Engonga Edjo'o ti i se adari ajọ to n ri si ọrọ aje ẹlẹkunjẹkun, Cema, o si jẹ abẹnugan lawujọ.
Ajafẹtọọ kan ni Equatorial Guinea, Nsang Christia Esimi Cruz, sọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ lo n tọka si òpin aarẹ Obiang.
Ọgbẹni Cruz sọ fun BBC pe igbakeji aarẹ n gbiyanju lati mu gbogbo eeyan to ba le ṣe idiwọ fun un lati di aarẹ ku l'ọna.

Oríṣun àwòrán, AFP
Igbakeji aarẹ ati iya rẹ l'awọn eeyan fura si wi pe wọn n wa gbogbo ọna lati gbegi dina ẹnikẹni to le ṣe idiwọ fun un lati de ipo aarẹ to fi mọ Gabriel Obiang Lima to jẹ ọmọkunrin Aarẹ mii amọ ti iya rẹ yatọ.
Gabriel ti jẹ minisita ileeṣẹ ijọba to n ri si epo rọbi fún ọdun mẹwaa.
A gbọ pe wọn ti lo fidio ri lati tabuku alatako lagbo oselu ni orile-ede Equatorial Guinea.
Ọkunrin kan to n jẹ Cruz ni ijọba le fẹ lo fidio to jade yii lati fi ote le itakun ayelujara nibi t'awọn eeyan ti n mọ ọpọ nnkan to n ṣẹlẹ.
Ijọba fofin de lilo itakun ayelujara loṣu Keje lẹyin ti iwọde bẹ silẹ ni Erekusu Annobón.
Ọgbẹni Cruz ni ọkunrin to ni Ibalopọ pẹlu awọn iyawo ile kii se nnkan tuntun, o ni eyi jẹ ọkan lara awọn àpẹẹrẹ iwa ibajẹ to gbode ni Equatorial Guinea.
Igbakeji aarẹ ti wọn ti fẹsun iwa ibajẹ kan naa pàṣẹ pe ki wọn fi ọwọ ofin mu ọmọkunrin Aarẹ mii lori ẹsun pe o ta baalu to jẹ ti ijọba.
Igbakeji ti wa pàṣẹ bayii wi pe ki cctv kamẹra wa kaakiri ileeṣẹ ijọba.
Bakanna lo tun paṣẹ pe ijọba yoo da ẹnikẹni to ba n ni Ibalopọ lọọfisi duro lẹnu iṣẹ.
Otitọ ni ohun ti igbakeji aarẹ sọ pe fidio to jade ti ba orukọ orilẹede Equatorial Guinea jẹ.
Lọjọ Aje to kọja, Equatorial Guinea wa lara awọn nnkan táwon n ka nipa rẹ julọ ni Naijiria, Kenya ati South Africa.
Ọgbẹni Cruz sọ pe iṣoro to n koju Equatorial Guinea ju ọrọ fidio ibalopọ to lu ori ayelujara pa lọ.
O ni fidio naa jẹ àpẹẹrẹ aisan to n ṣe orilẹede naa, kii ṣe aisan gan an gan an.















