Mọ̀ nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wọlé ìbò ní Amẹ́ríkà àti Australia

Segun Adeyina, Chiaka Barry, Yemi Mobolade àti Chiaka Barry

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà nílẹ̀ òkèrè ìyẹn Nigerians in Diaspora Commission (NiDCOM) ti kan sáárá sáwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà nílẹ̀ òkèrè tí wọ́n ṣe àṣeyọrí níbi ètò ìdìbò.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́rin, Dókítà Oye Owolewa (Ẹkùn Columbia, USA), Chiaka Barry (Ẹkùn Ginninderra, Australia), Segun Adeyina (Georgia, USA) àti Yemi Mobolade (Colorado Springs, USA) ni wọ́n jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò tí wọ́n kópa níbẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ NiDCOM Abdur-Rahman Balogun fi léde ní adarí àjọ náà, Abike Dabiri-Erewa gbóríyìn fún ìjáwé olúborí àwọn àwọn ọmọ Nàìjíríà náà.

Dabiri-Erewa ní nǹkan ìwúrí ni pé àwọn ọmọ Nàìjíríà náà fi ìtàn balẹ̀ lágbo òṣèlú ní agbègbè tí kóówá wọn wà.

Dókítà Oye Owolewa ni wọ́n tún dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojù ẹkùn Columbia lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà nígbà tí wọ́n dìbò yan Chiaka Barry sí ilé aṣòfin Australian Capital Territory (ACT) láti ṣojú ẹkùn Ginnindera lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Liberal Party.

Segun Adeyina ni wọ́n tún dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú ìpínlẹ̀ District 110 ní Georgia, Amẹ́ríkà.

Wọ́n dìbò yan Adeyemi Mobolade láti di Mayor ti Colorado Springs lọ́dún 2023, ní èyí tó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí adúláwọ̀ yóò kọ́kọ́ de ipò náà.

Ta ni àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n dìbò yàn yìí?

Oye Owolewa

Oye Owolewa

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ọdún 1989 ni wọ́n bí Adeoye Owolewa ní ìlú Boston, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Ọmọ bíbí ìlú Omu-Aran ní ìpínlẹ̀ Kwara ni bàbá rẹ̀, tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ bíbí Ilesa ní ìpínlẹ̀ Osun.

Ìlú Newton ní Massachusetts ni wọ́n ti tọ dàgbà níbẹ̀ ló si ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Boston Latin School tó sì parí lọ́dún 2008.

Ọdún 2014 ló gboyè ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìpoògùn ní ilé ẹ̀kọ́ Northeastern University, tó sì tẹ̀síwájú láti lọ máa gbé ní Washington. Ọdún yìí kan náà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa oògùn.

Nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2020 ni wọ́n kọ́kọ́ dìbò yàn-án gẹ́gẹ́ bí “shadow representative” n’ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, kí wọ́n tún dìbò yàn-án fún sáà kejì.

Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat ni Oye Owolewa.

Segun Adeyina

Segun Adeyina

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ọdún 2022 ni wọ́n dìbò yan Segun Adeyina gẹ́gẹ́ bí aṣòfin ní ilé aṣòfin Georgia House of Representatives.

Ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kìíní, ọdún 2023 lo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ aṣòfin lábẹ́ ẹgbẹ́ oṣèlú Democrat.

Akẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ nípa iná mọ̀nàmọ́ná ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Akron, Ohio ni Adeyina.

Bákan náà ló gba ipò kejì nínú ìmọ̀ “management information systems” ní ilé ẹ̀kọ́ Lawrence Technology University.

Federal Government College, Ilorin ni Adeyina ti jáde ẹ̀kọ́ girama lọ́dún 1986, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Physics ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Eko kó tó tẹ̀síwájú lọ sí Amẹ́ríkà.

Yemi Mobolade

Yemi Mobolade

Oríṣun àwòrán, yewmiformayor/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdún 1979 ni wọ́n bí Blessing Adeyemi Mobolade ní ìpínlẹ̀ Eko, tó sì dàgbà síbẹ̀.

Òun ni Mayor kejìlélógójì fún Colorado Springs, Colorado nígbà tí wọ́n búra wọlé fún-un lọ́jọ́ Kẹfà oṣù Kẹfà ọdún 2023.

Ó jẹ́ aláwọ̀dúdú tó máa kọ́kọ́ dépò mayor Colorado Springs àti olóṣèlú àkọ́kọ́ tí kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican tó máa kọ́kọ́ dé ipò náà.

Onímọ̀ nípa ètò ìsúná, tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ExxonMobil ni bàbá Mobolade, tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ olùkọ́.

Ọdún 1996 ló fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ láti lọ máa gbé ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ Bethel University lọ́dún 2001.

Ó gba oyè onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ Indiana Wesleyan University àti A. W. Theological Seminary ní Simpson University.

Lọ́dún 2010 ni Mobolade kó lọ sí Colorado Springs níbi tó da ilé oúnjẹ àti ilé ìjọsìn sílẹ̀ sí.

Nínú oṣù Kẹrin, ọdún 2022 ni Mobolade kéde pé òun fẹ́ díje fún ipò mayor Colorado Springs gẹ́gẹ́ bí oló ṣèlú tó dá dúró láì ní ẹgbẹ́ òṣèlú kankan.

Ọdún 2017 ni Mobolade di ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Chiaka Barry

Chiaka Barry

Oríṣun àwòrán, Chiaka Barry/Instagram

Ọmọ Nàìjíríà tó fi orílẹ̀ èdè Australia ṣe ibùjókòó ni Chiaka Barry.

Aṣòfin ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Australian Capital Territory tó ń ṣojú ẹkùn Ginnindera lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Canberra Liberals ni Chiaka Barry.

Òun ló gba ipò lọ́wọ́ Elizabeth Kikkert lẹ́yìn tí wọ́n gba tíkẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́ rẹ̀.

Ọdún 2008 ni Barry kó lọ sí Australia láti United Kingdom, tó sì ń gbé ní Canberra láti ìgbà náà.