John Akinmurele, òṣìṣẹ́ àjọ DSS tó fẹ́ di gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
Eto idibo yoo waye lati yan gomina tuntun fun ipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2024.
Lara awọn to n dije fun aga yii ni John Otitọju Akinmurele ti o n dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu, Young Peoples Party, YPP.
Ọmọ ilu Ilu Tuntun ni agbegbe ijọba ibilẹ Okitipupa.
Ninu ọrọ to ba BBC bews Yoruba, Ọgbẹni Akinmurele ṣalaye pe ileeṣẹ ẹṣọ alaabo DSS loun kọkọ ba ṣiṣẹ ni ibẹrẹ pẹlẹ aye oun ki oun to kọwe fi iṣẹ silẹ lọdun mẹta sẹyin lẹyin iṣẹ ọdun mẹtala.
O ni ko yẹ ko ya awọn eeyan kan lẹnu nigba ti wọn ba gbọ pe oun di gomina nipasẹ ibo araalu nitori pe “Awọn nnkan to n ṣiṣẹ fun wa ju nnkan ti awọn eeyan n fi oju ri lọ.
Oludije ẹgbẹ oṣelu YPP naa ṣalaye pe oun kii ṣe ajeeji si akoso ati wi pe o ti pẹ ti oun ti n wa ni imurasilẹ fun akoso ipinlẹ Ondo.
O ṣe afikun rẹ pe eredi ilepa oun lati di gomina wa lati le e jẹ oun fun awọn ti ko ni ohun ti aye le gbọ fun irora wọn; ati lati jẹ iranlọwọ fun awọn ti ko ni iranlọwọ.
- Ẹ má dìbò, kẹ́ ẹ́ sebẹ̀ l‘Ondo, èmi ni kí ẹ dìbò gómìnà fún, kí àyípadà rèrè le è wà - Agboola Ajayi
- Èmi kò ní ṣe akótilétà ọmọ ọ̀dọ̀, tẹ́ ẹ bá dìbò fún mí gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo - Mimiko
- Bí mo bá wọlé gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ondo, mo máa kọ́ ojú òpó ọkọ̀ ojú irin sí orí omi – Kunle Ajayi, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú AAC
- Kí ló dé tí Seyi Makinde àti INEC tahùn sí ara wọn lórí ìdìbò gómìnà l‘Ondo?
- Kí ni ìdí tí PDP sẹ fẹ́ kí INEC pààrọ̀ ọ̀gá àgbà ọọ́físì rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo?
'Ọlọrun da ipinlẹ Ondo ni adatan, amọ ipin Ondo wa lara ipinlẹ to rẹyin julọ ni Naijiria'

Ọgbẹni Akinmurele ni gbogbo nnkan ti awọn awujọ to n ni ilọsiwaju ni, bii ohun alumọni ati awọn eniyan ọlọpọlọ pipe ni Eleduwa fi jinkin ipinlẹ Ondo. O fi kun un pe ohun to han fun oju ri naa ni pe pẹlu gbogbo awọn ọrọ wọnyii, ipo ẹyin ni ipinlẹ Ondo wa lawujọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria.
O ni ọkan gboogi lara ipenija to n ranju mọọ mọ ipinlẹ Ondo ni ọr abo, eleyi to ni oun yoo lo awọn iriri oun lẹka naa lati wa ojuutu si, iyẹn bi oun ba wọle gẹgẹ bi i gomina ipinlẹ naa.
“Ti abo ba ti wa, ati mu idagbasoke ba ilu; ati pe awọn miran wa ba wa gbe yoo jẹ nnkan to rọrun.”
Bakan naa lo ni oun yoo mojuto ọrọ ẹkọ ki o le jẹ eyi ti tẹrutọmọ yoo lanfani si.






