Èyí làwọn ìpínlẹ̀ tó ṣeéṣe kó faragbá ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fẹ́ gùnlé nítorí àìfẹ́ san owó oṣù tuntun

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Joe Ajaero

Oríṣun àwòrán, NLC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà, Nigeria Labour Congress, NLC ti sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí gómìnà wọn kò bá ì tíì máa owó ọsù kéré jùlọ ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà (N70,000) láti gúnlè ìyanṣẹ́lódì bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kìíní oṣù Kejìlá.

Ìdarí yìí ló ń wáyé lẹ́yìn àpérò ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣe lópin ọ̀sẹ̀.

NLC ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fáwọn pé àwọn gómìnà kan kò ì tíì bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó oṣù tuntun pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe le koko ní Nàìjíríà lásìkò yìí.

Wọ́n ní àwọn gómìnà náà ń tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀, pé wọn kò ní ọ̀wọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ rárá àti pé gbogbo ètò táwọn ìjọba ń ṣe lásìkò yìí ló ń kó ìnira bá àwọn èèyàn tó yàn sípò.

Èyí ló mú kí NLC láti darí àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ tí ìjọba kò bá ì tíì máa san owó náà láti gúnlè ìyanṣẹ́lódì.

Ẹ ó rántí pé ní oṣù Keje, ọdún 2024 ni ààrẹ Bola Tinubu buwọ́lu ẹgbẹ̀rún àádọ́rin náírà (N70,000) gẹ́gẹ́ bí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ.

Láti ìgbà náà ni àwọn gómìnà kan ti ńn kàn sáwọn èèyàn wọn ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti fẹnukò lórí iye tí wọn yóò máa san fáwọn òṣìṣẹ́.

Àwọn gómìnà kan ti gbà láti san iye tí ìjọba àpapọ̀ buwọ́lu, táwọn mìíràn sì ti kéde iye tó ju ti ìjọba àpapọ̀ lọ.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kọkànlá tí a wà yìí, àwọn ìpínlẹ̀ tó lé ní ogún ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó oṣù tuntun náà fáwọn òṣìṣẹ́ nígbà táwọn mìíràn kò ì tíì bẹ̀rẹ̀ rárá.

Lára àwọn ìpínlẹ̀ tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó oṣù tó kéré jùlọ nìwọ̀nyí:

  • Lagos state – N85,000
  • Rivers state — N85,000
  • Bayelsa state – N80,000
  • Niger – N80,000
  • Enugu – N80,000
  • Akwa Ibom state – 80,000
  • Abia – N70,000
  • Adamawa – N70,000
  • Anambra – N70,000
  • Jigawa – N70,000
  • Borno – N70,000
  • Ebonyi – N75,000
  • Edo – N70,000
  • Delta – N77,000
  • Gombe – N71,000
  • Ogun – N77,000
  • Kebbi – N75,000
  • Ondo – N73,000
  • Kogi – N72,000
  • Kwara – N70,000

Àwọn ìpínlẹ̀ tó ṣeéṣe kí ìyànṣelódì ti wáyé tí wọn kò bá san owó oṣù tuntun fáwọn òṣìṣẹ́ ní ìparí oṣù Kọkànlá ni:

  • Bauchi
  • Benue
  • Cross River
  • Ekiti
  • Imo
  • Kaduna
  • Kano
  • Katsina
  • Nasarawa
  • Osun
  • Oyo
  • Plateau
  • Sokoto
  • Taraba
  • Yobe
  • Zamfara