Agbéṣùmọ̀mí tó wọ àdó olóró pa ara rẹ̀ àti èèyàn 25 míì

Oríṣun àwòrán, EPA
Ijọba Pakistan ti kede pe eeyan marundinlọgbọn lo ti jade laye lẹyin ado oloro to bu gbamu nibudokọ ọkọ oju irin kan lagbegbe Balochistan.
Yatọ si awọn to ku, ọpọ awọn mii lo farapa yanayana ninu ibugbamu naa to waye laarọ kutu lasiko ti ọpọ eeyan n wọ ọkọ ọhun lati Quetta lọ si Balochistan.
Ẹgbẹ ajijagbara kan, Balochistan Liberation Army, ti kede pe awọn lo wa nidi ikọlu naa.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ẹnu lọlọ yii ni oniruru ikọlu n waye lagbegbe ti iṣẹlẹ yii ti waye latari bi awọn kan ṣe n bere fun ominira ati anfani lati maa ṣakoso ohun ini wọn funra wọn.
Aṣoju ijọba ipinlẹ ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe aadọta eeyan lo farapa, ti ẹṣin ko kọ iku to ṣiṣẹ naa si jade laye.
Ọga ọlọpaa, Muhammad Baloch, ni ibugbamu naa ko ṣẹyin ẹnikan to wọ ado oloro ti iwọn rẹ to kilo mẹfa si mẹjọ.
Baloch sọ fun BBC pe lara awọn to ku ni araalu ati ọmọ ogun.
Awọn fidio ori ayelujara ṣafihan bi ibugbamu naa ṣe waye nibi ti ọpọ eeyan korajọ si laarọ ọjọ Abamẹta.
Ọkunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Abdul Jabbar sọ pe oun ti ra tikẹeoti oun, asiko ti oun n wọ ẹnu abawọle ibudokọ ọkọ oju irin naa ni ibugbamu ọhun waye.
Jabbar ṣalaye pe oun ko tii ri irufẹ nnkan bẹẹ ri nile aye oun ati pe ẹru ba oun gidi ti oun ko si le gbagbe ohun ti oun ri titi lai.















