Johnny Somali, gbajúmọ̀ ọ̀dọ́kùnrin tó ń rìn ní bèbè ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tó fi ẹnu ko ère kan lẹ́nu

Oríṣun àwòrán, Johnny Somali/Instagram
Ọdọmọkunrin kan to jẹ gbajumọ ori itakun ayelujara YouTube, Johnny Somali, ti wọ gau lẹyin to fẹnu ko ere kan to n ṣapejuwe bi awọn ọmogun Japan ṣe huwa ipa to nii ṣe pẹlu Ibalopọ s'awọn obinrin Korea lasiko ti Japan fi n ṣe akoso Korea.
Lasiko to ṣabẹwo si gbagede aṣa ati itan nílu Seoul ni Somali f'ẹnu ko ere naa lẹnu ti o si ya fọto pẹlu ere ọhun.
Lọjọ kẹsan an oṣu Kẹwaa ni Somali fi fidio to ṣe nigba to fẹnu ko ere naa lẹnu sori ayelujara.
Ijọba Korea maa n ṣe iranti ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọdọbinrin tawọn ọm'ogun Japan huwa ipa Ibalopọ si laarin ọdun 1910 si 1945 ti Japan fi ṣakoso Korea.
Johnny Somali tọrọ aforijin
Gẹgẹ bi iwe iroyin Korea Times ṣe sọ, Somali ti tọrọ aforijin fun ohun to ṣe.
O lọ duro lẹgbẹ ere yii ti o si fori balẹ fawọn eeyan Korea.
"Mo tọrọ aforijin lọwọ awon eeyan Korea, mi o mọ iṣepataki ere yii lo jẹ ki n huwa bẹẹ."
O ni ohun tóun ni lọkan ni lati pa awọn eeyan Amẹrika lẹrin in.
Somali ni lootọọ ihuwasi oun tabuku awọn eeyan Korea.
Bo tilẹ jẹ pe Somali ti tọrọ aforijin, ọpọ ọmọbibi orilẹede Korea lo sọ pe ko dawọn loju pe aforijin naa to ṣe ti inu ọkan rẹ wa.
Ọpọ lo n sọ pe ko tii gbe fidio naa kuro lori ayelujara lẹyin to tọrọ aforijin tan.
Lara awọn nǹkan to wa loju opo ayelujara Somali ni fọto Olootu ijọba Japan tẹlẹ, Shinzo Abe pẹlu akọle - "Mo ṣẹgun awọn eeyan Korea fun yin," Shinzo Abe.
Awọn eeyan kan sọ pe lẹyin to ti yọ fídíò ori YouTube kuro tan, fọto ati ọrọ to kọ sibẹ si wa loju opo Instagram rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ẹsun ti wọn fi kan Johnny Somali
Ni bayii, iwadii ti bẹrẹ lori Somali ẹni ti orukọ rẹ gan gan an n jẹ Ramsey Khalid Ismael fun didena okowo.
Lara ẹsun ti wọn tun fi kan Somali ni ni lilo oogun oloro.
Ẹwẹ, ijọba Korea ti gbẹsẹ le iwe irinna Somali nigba ti iwadii n lọ lọwọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Ijọba ṣe eleyii ki o maa baa raye salọ lati Korea titi ti iwadii to n lọ yoo fi pari.
Ohun ti a gbọ lati Korea ni pe Somali le fi ẹwọn ọdun mẹwaa jura ti o ba jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.















