Wizkid, Burna Boy, Asake, Yemi Alade Davido rí ìforúkọsílẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Grammy

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ètò ìfúnni lámì ẹ̀yẹ àwọn olórin ti àgbáyé ìyẹn Grammy Awards ti kéde àwọn ori tó làmì laaka tí wọ́n yóò gba àmì ẹ̀yẹ ti ọdún yìí.
Ní ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n kéde àwọn orin tí wọ́n fi orúkọ wọn sílẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé tó fi mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n máa ń bu iyì fún àmì ẹ̀yẹ yìí nítorí ojú táwọn èèyàn fi máa ń wò ó.
Ní ìpele orin ilẹ̀ Áfíríkà, Davido, Wizkid, Burna Boy, Tems, Yemi Alade, Lojay àti Asake ni àwọn tí wọ́n gba àwọ orin wọn wọlé fún ti ọdún yìí.
Gbajúmọ̀ olórin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Beyoncé ló ní àkọ́ọ́lẹ̀ iye ìgbà tí wọ́n fi orin rẹ̀ sílẹ̀ jùlọ ní ìpele ọ̀nà mọ́kànlá.
Díẹ̀ lára àwọn orin tó wà ni ipele kọ̀ọ̀kan lọ́dùn yìi ni:
Orin ilẹ̀ Áfírikà tó dára jùlọ
- Tomorrow - Yemi Alade
- MMS - Asake & Wizkid
- Sensational - Chris Brown ft Davido & Lojay
- Higher - Burna Boy
- Love Me Jeje - Tems
Àwo orin tó dára jùlọ nínú ọdún
- New Blue Sun – Andre 3000
- Cowboy Carter – Beyonce
- Short n’ Sweet – Sabrina Carpenter
- Brat – Charli XCX
- Djesse Vol. 4 – Jacob Collier
- Hit Me Hard and Soft – Billie Eilish
- The Rise and Fall of a Midwest Princess – Chappell Roan
- The Tortured Poets Department – Taylor Swift
Àwo orin tó dára jùlọ ní àgbáye
- Alkebulan II - Matt B feat. Royal Philharmonic Orchestra
- Paisajes - Ciro Hurtado
- HEIS - Rema
- Historias De Un Flamenco - Antonio Rey
- Born In The Wild – Tems
Orin tó làmì laaka lọ́dún
- A bar song (Tipsy)
- Birds of a feather
- Die With A Smile
- Fortnight
- Good Luck Bane
- Not like Us
- Please Please Please
- Texas Hold’em
Ẹni tó mọ orin kọ sílẹ̀ jùlọ
- Jessi Alexander
- Amy Allen
- Edgar Barrera
- Jessie Jo Dillon
- Raye
Fídiò orin tó dára jùlọ
- Tailor Swift - A$AP Rocky; Vania Heymann & Gal Muggia, video directors
- 360 - Charli xcx; Aidan Zamiri, video director; Jami Arceo & Evan Thicke, video producers
- Houdini - Eminem; Rich Lee, video director; Kathy Angstadt, Lisa Arianna & Justin Diener, video producers
- Not Like Us - Kendrick Lamar; Dave Free & Kendrick Lamar, video directors; Jack Begert, Sam Canter & Jamie Rabineau, video producers
- Fortnight - Taylor Swift feat. Post Malone; Taylor Swift, video director; Jil Hardin,








