Fídíò tó ṣàfihàn b'awọn sọ́jà kan ṣe ń ṣá ara eeyan ní ìṣáákùṣá gbòde, àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ọmogun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní Bukina Faso

Aworan Paul Henri-Damiba

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọm'ogun orilẹede Burkina Faso ti bẹrẹ iwadii lori fidio kan eyi to ṣafihan b'awọn sọja kan ṣe n ṣa ara eeyan ni iṣakuṣa.

Ko si ẹni to le sọ ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye tabi mọ awọn to wa ninu fidio naa to ti n tan kaakiri itakun ayelujara.

Amọ, ohun to daju ni pe lara awọn to wa ninu fidio naa wọ aṣọ ṣọja.

Ọga agba ileeṣẹ ọm'ogun Burkina Faso, Ogagun Celestin Simpore sọ pe ileeṣẹ ologun ti ni káwọn akọṣẹmọṣẹ ṣe iwadii lori fidio naa, ki wọn si sọ nnkan to bi fọnran ọhun gan an.

"Ihuwasi awọn sọja ninu fidio naa tako alakalẹ ati ofin ileeṣẹ ologun.

Awọn to wa ninu fidio yoo foju wina ofin, ti a ba fi le fidi rẹ múlẹ," Ọgagun lo sọ bẹẹ.

Loṣu Keje to kọja lọ ni ileeṣẹ ọm'ogun Burkina Faso bu ẹnu ẹtẹ lu bi afurasi sọja kan ṣe n ṣe oku eeyan baṣu baṣu.

Awọn ajọ ajafẹtọọ ti maa n kilọ fun ileeṣẹ ọm'ogun lori ẹsun fifi ẹmi awọn eeyan ṣofo, ṣugbọn wọn maa n saba dibọn.

Ileese ọm'ogun maa n saba sọ pe awọn eeyan kan lo maa n lo asọ ologun lati ṣiṣẹ laabi yii.

Loṣu Kẹrin to koja ni ajọ ajafẹtọọ fẹsun kan awọn ọmogun Burkina Babe pe wọn ṣeku pa araalu 223 eyi ti ọmọde 56 wa ninu wọn.

O le ni miliọnu meji araalu ti wọn ti sa kuro nile wọn lati ọdun 2015 nitori rogbodiyan t'awọn ẹgbẹ ajijagbara ati alakatakiti ẹsìn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu al-Qaeda ati ISS da silẹ.

Eeyan to le ni 26,000 l'awọn agbesunmọmi ti gbẹmi wọn, 13,000 ninu wọn lo ku lati igba ti iditẹgbajọba ti waye ni oṣu Kẹsán an ọdun 2022.