Wo bí o ṣe lè dá àwọn ayédèrú ‘travel agents’ mọ̀ tí o bá fẹ́ Japa lọ ṣiṣẹ́ ní US, UK tàbí Canada

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọrọ irinajo lọ silẹ okere lọna ati gbe igbeaye irọrun wa lara awọn nnkan ti awọn ọmọ Naijiria n jẹ lẹnu julọ lasiko yii.
Laye atijọ, ti awọn eeyan ba rinrinajo lọ ilẹ okeere, o maa n jẹ lati kẹkọọ, lati lọ gbafẹ tabi lati lọ ki awọn eeyan wọn to wa lọhun, amọ bayii ṣe lawọn eeyan n ko gbogbo mọlẹbi wọn lọ soke okun.
Eyii ko ṣẹyin bii nnkan ṣe ri ni Naijiria nipa eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ati eto abo to mẹhẹ.
Naijiria, to jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti ọrọ aje rẹ tobi julọ nilẹ adulawo lo n koju iṣoro airiṣẹṣe awọn ọdọ, awọn to niṣẹ lọwọ gan, owo oṣu wọn ko to nnkan, eyii to n mu ki ọpọ ninu awọn ọdọ naa maa japa.
Ni bayi ti awọn eeyan n japa lọ silẹ okere fun igbeaye to dara, pupọ ninu awọn to n japa ọhun lo n lo awọn oṣiṣe eto irinna ti ọpọ mọ si ‘travel agents’ lati ba wọn to iwe wọn.
Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn ‘travel agents’ naa lo jẹ olootọ, ọpọ ninu wọn naa lo jẹ onijibiti to maa n tan awọn eeyan lati gba owo lọwọ wọn, ti wọn a si ta awọn onibara wọn si oko ẹru.
“Ayederu flight ticket ni agent mi fun mi”
Ọkan lara awọn eeyan to ṣalabapade ayederu oṣiṣe eto irinna ni ọdọbinrin kan to sọ iriri rẹ fun BBC.
O ni “Agent mi kii ṣe olododo eeyan, o fun mi ni ayederu tikẹẹti lati fi wọ baalu.
“Mi o si mọ pe ayederu ni tikẹẹti ọhun titi di igba ti mo de papakọ ofurufu ti mo fẹ wọ baalu.
“Awọn oṣiṣẹ ọkọ ofurufu naa sọ fun mi pe ko si ọkọ kankan to n rinrinajo pẹlu nọmba to wa lori tikẹẹti mi, nigba ti mo pe ẹni to ba mi ra tikẹẹti naa, ni ṣe lo tun parọ fun mi.
“Lẹyinorẹyin, ṣe ni mo tun lọ f owo ara mi ra tikẹẹti miran… niṣe lo tan mi jẹ.”
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn ajọ iṣọka agbaye to n ri si irinajọ lati orilẹ-ede kan si omiran, United Nations Migration Agency, ati International Organisation for Migration, IOM, sọ ninu atẹjade kan pe o le ni ẹgbẹrun kan ọmọ Naijiria ti awọn oṣiṣẹ eto irinna ti tan jẹ lori igbiyanju wọn lati lọ silẹ Gẹẹsi.
Adari ajọ IOM, Laurent De Boeck, wa ke si awọn ọmọ Naijiria ki wọn la oju wọn daadaa, ki wọn si ṣe iwadii to tọ ki wọn to sọ pe awọn fẹ lọ silẹ okeere.
Bawo ni o ṣe le da awọn ayederu ‘travel agent’ mọ?
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Gbarale Louis Suzor to jẹ onimọ nipa irinjo okeere, o ni o ṣoro lati da ayederu oṣiṣẹ eto irina mọ.
Suzor sọ fun BBC pe pupọ ninu awọn eeyan ọhun lo ni ohun ti wọn le fi han fun eeyan pe ojulowo ni wọn amọ arinrinajo lo gbọdọ mọ ohun to n fẹ, ko si ṣe awọn iwadii to yẹ ko ṣelaye ara re.
Lara awọn apẹrẹ ti Suzor sọ pe ẹni to ba fẹ rinrinajo gbọdọ fura si ree.
Bibere fun owo gọbọi ṣaaju igbesẹ irinajo: Suzor sọ pe ti oṣiṣẹ eto irinna ba n bere owo gọbọi ko to bẹrẹ igbesẹ irinajo mu ifura lọwọ.
“Awọn ojulowo yoo sọ gbogbo ohun to yẹ ki o mọ fun ọ, wọn yoo fun ọ ni aridaju pe ohun ti o n lepa yoo bọ si, lẹyin naa ni wọn yoo bere owo lọwọ rẹ.”
Ẹri to daju: Ri daju pe gbogbo ohun ti ‘agent’ n sọ fun ọ jẹ ohun ti o le ṣewadii rẹ ti iwọ naa yoo si ri ẹri to daju nipa rẹ.
Ti wọn ba sọ irufẹ iṣẹ ti o maa lọ ṣe loke okun, bere orukọ ileeṣẹ naa ki o si ṣayẹwo ileeṣẹ ọhun pẹlu Google ati loju opo Facebook, X, Instagram, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ede orilẹ-ede ti o n lọ: Ti o ba fẹ lọ si orilẹ-ede ti wọn kii sọ ede ti o gbọ bii ede Gẹẹsi, wa ẹni to gbọ ede ilẹ naa ko ba ọ ṣe iwadii nipa orilẹ-ede ọhun loju opo ayelujara ‘website’ wọn.
Imọ ẹrọ ti mu ko rọrun laye ode oni lati le tumọ ede ilẹ miran pẹlu Google Tranlate.
O le lo ẹrọ naa lati wa imọ si loju opo orilẹ-ede ti o n lọ.
Lakotan, maṣe gbẹkẹle ọrọ ‘travel agent’ rẹ nikan.
Iwọ funra rẹ gbọdọ ṣe awọn iwadii to tọ laye ara rẹ ki o ma baa ko sọwọ gbajuẹ tabi di ẹni ti wọn n ta si oko ẹru.














