₦87.9trn ni àpapọ̀ iye gbèsè tí Naijiria jẹ báyìí – Debt Management Office

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Nigba ti yoo fi di inu oṣu Kẹsan an ọdun 2023 yii, iye gbese ti Naijiria jẹ ti le ni tiriliọnu mẹtadinlaadọrun un naira.
Ọọfisi ajọ to n bojuto gbese ni Naijiria, Debt Management Office (DMO), lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan.
DMO ni gbese naa jẹ apapọ gbese Naijiria labẹle ati loke okun, to fi mọ gbogbo gbese awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ati ilu Abuja.
Eyii n tumọ si pe gbese Naijiria le si ni ida 0.61% laarin oṣu Kẹfa si oṣu Kẹsan an, ọdun 2023.
Atẹjade ọhun ni “Adinku ba iye gbese ti a jẹ loke okun lati $43.16b ni ogbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 si $41.59b ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023.
“Nigba ti gbese naa si le si labẹle pẹlu ₦1.80trn.
DMO ni gbese Naijiria loke okun din diẹ si latari irapada owo ‘Eurobond’ ti iye rẹ jẹ ẹẹdẹgbẹta (500) miliọnu dọlati Naijiria ṣe.

Oríṣun àwòrán, DMO
Yatọ si Eurobound ọhun, Naijiria tun san $413.859 miliọnu pada lara $3.4 biliọnu to ya lọwọ ajọ International Monetary Fund lasiko ajakalẹ arun Covid-19 lọdun 2020.
DMO sọ siwaju siwaju si pe bi Naijiria ṣe n san awọn gbese rẹ safihan pe ijọba apapọ ti ṣetan lati ko awọn ọmọ Naijiria kuro loko gbese.
Ẹwẹ, o fi kun pe o ṣe pataki ki ijọba wa awọn ọna tuntun ti yoo maa fi pa owo wọle ko le bọ loko gbese patapata.














