Ohun tí a mọ̀ rèé nípa àdéhùn ìdáwọ́dúró ogun láàrín Israel àti ikọ̀ agbébọn Hezbollah

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Joe Biden ti kede adehun jogun-o-sinmi laarin orilẹede Israel atawọn ọmọogun Hezbollah eyi ti yoo mu idawọduro ba ogun oṣu mẹtala to ti n waye laarin ikọ ọmọogun Israel ati ikọ agbebọn Hezebollah ti orilẹede Iran n ṣe agbatẹru fun.
Ninu atẹjade kan ti orilẹede Amẹrika ati France fi sita, wọn ni adehun naa yoo mu idawọduro ba ija to n waye lorilẹede Lebanon, yoo si tun “daabo bo Israel lọwọ gulegule ẹgbẹ Hezbollah atawọn ẹgbẹ agbesunmọmi miran”.
Ohun ti a mọ niyi nipa adehun alaafia naa lati inu awọn ipade iroyin gbogbo ati iroyin kaakiri awọn ileeṣẹ iroyin to ṣe e fọkan tan.
Adehun idawọduro ogun naa yoo fẹsẹ rinlẹ
Aarẹ orilẹede Amlẹrika, Joe Biden sọ fun awọn akọroyin pe “adehn naa jẹ eyi ti wọn ṣe eto rẹ lati fi ẹsẹ rinlẹ daradara”.
Labẹ awọn gbendeke to wa ninu adehun ọhun, laarin ọgọta ọjọ, ikọ agbebọn Hezbollah yoo ko awọn ọmọogun ati ohun ija oloro rẹ kuro ni agbegbe ti wọn ya sọtọ gẹgẹ bi Blue line – iyẹn aala ilẹ laarin Lebanon ati Israel - titi de agbegbe odo Litani, to wa ni nnkan bii ogun ibusọ si iha ariwa.
Awọn ọmọ ogun orilẹede Lebanon ni yoorọpo awọn ọmọ ogun agbebọn Hezbolla to wa lawọn agbegbe naa, wọn yoo si rii daju pe gbogbo awọn eroja ogun wọn ni wọn ko kuro ti wọn ko si le tu u kọ pada mọ, gẹgẹ bi agbagb oṣiṣẹ ilẹ Amẹrika kan ṣe sọ.
Laarin ọgọta ọjọ naa, Israel pẹlu yoo ko awọn ọmọ ogun rẹ to ku, gẹgẹ bi Biden ṣe sọ, o fi kun un pe eyi yoo fun awọn olugbe agbegbe mejeeji aala ilẹ naa lanfani ati pada si ile wọn.

Ẹgbẹrun marun un ọmọogun Lebanon ni yoo rọpo awọn ọmọogun Hezbollah
Ọmọogun ẹgbẹrun marun un ni ireti wa pe orilẹede Lebanon yoo ko ranṣẹ si ẹkun gusu ilẹ naa labẹ iṣakoso adehun yii.
Amọṣa ibeere ṣi n waye lori ohun ti yoo jẹ ojuṣe wọn ati boya wọn yoo laṣẹ lati koju awọn ọmọ ogun agbebọn Hezbollah bi o ba nilo ki wọn gbe igbesẹ.
Ileeṣẹ ọmọogun Lebanon ni awọn ko ni ohun ija to to lati ṣe ojuṣe wọn labẹ adehun tuntun naa.
Amẹrika ati France yoo ṣe amojuto adehun alaafia naa
Adehun yii wa ni ibamu pẹlu afẹnuko 1701 ti gbimọ abo ajọ iṣọkan agbaye to dopin laarin Israel ati Hezbollah lọdun 2006.
Labẹ afẹnuko naa, awọn agbegbe to wa ni gusu Litani ko gbọdọ ni awọn ọmọogun tabi nnkan ogun kankan yatọ si awọn ọmọ ogun Lebanon ati ikọ ọmọogun apẹtusaawọ ajọiṣọkan agbaye(Unifil).
Amọṣa igun mejeeji ni wọn n fi ẹsun kan ara wọn pe wọn ko tẹle afẹnuko naa.
Israel sọ pe wọn fi aye gba Hezbollah lati kọ awọn ile si agbegbe naa, bẹẹ naa ni hezbollah pẹlu n sọ pe Israel n fi awọn baluu ogun rẹ fo kaakiri agbegbe naa.
Amọṣa, lọtẹ yii, orilẹede Amẹrika ati France ti sọ pe oun yoo darapọ mọ igbesẹ tuntun yii, awọn yoo si mojuto igbesẹ gbogbo to rẹ mọ titẹle e.
Biden ni: “ ko ni si aye fun Hezbollah lati kọ ohunkohun si agbegbe gusu Lebanon.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Israel ni awọn yoo gbe igbesẹ bi Hezbollah ba ṣe lodi si adehun naa
Olootu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu sọ pe Israel yoo “ni anfani lati lo awọn ọmọogun rẹ” ni Lebanon “pẹlu ajọmọ orilẹede Amẹrika”.
“Bi Hezbollah bá ṣe lodi si adehun tabi gbiyanju lati ko nnkan ogun tabi wa nnkan ijagun fun ara rẹ, a maa kọlu wọn, bi o ba gbiyanju lati kọ awọn ile kankan lagbegbe aala ilẹ rẹ, a maa kọlu wọn. Bi wọn ba ju ado oloro, bi wọn ba gbẹ iho aja ilẹ, bi wọn ba gbe ọkọ to n ko nnkan ogun wọle, a maa kọlu wọn,”
Aarẹ Biden fi ara mọ ipinnu yii ninu ọr to ba awọn akọroyin sọ: “Bi Hezbollah tabi ẹnikẹni ba ṣe lodi si adehun yii tabi gbe ikọlu dide si orilẹede Israel, a jẹ pe orilẹede Israel ni ẹtọ lati daabo bo ara rẹ ni ibamu pẹlu ofin orilẹede agbaye.”












