Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn kan, àwọn mẹ́rin farapa lórí Third Mainland Bridge

Oríṣun àwòrán, LASTMA/X
Àjọ tó ń rí sí ìrìnnà ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Eko, Lagos State Traffic Management Authority, LASTMA, ti kéde pé ìjàmbá ọkọ̀ kan tó wáyé lórí afárá Third Mainland Bridge.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ LASTMA, Adebayo Taofiq fi sójú òpó X wọn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlógún ní àwọn ọkọ̀ ńlá méjì bọ́ọ̀sì J5 Ford (FKJ 724 YC) àti mẹ́sídíìsì (FKJ 746 YC) ni wọ́n kọlu ara wọn ní agbègbè Ilubinrin, tí èèyàn bá ń wọ Sura lọ.
LASTMA ní èèyàn kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, táwọn mẹ́rin mìíràn sì farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ náà.
Ó ní àwọn èèyàn tó ń kọjá lọ náà ṣe àtìlẹyìn fáwọn láti rí àwọn èèyàn tó wà nínú ìjàmbá náà yọ.
Ó sọ pé èèyàn mẹ́ta nínú àwọn mẹ́rin tó wà nínú ọkọ̀ J5 ni àwọn rí yọ ní ààyè àmọ́ tí àwọn kò rí èèyàn kan yọ látàrí bí àwọn ẹrù tó wà nínú ọkọ̀ náà ṣe ti dà le lórí.
Ó fi kun pé ìwádìí ṣàfihàn pé ìjánu ọkọ̀ (bíréèkì) J5 Ford ló ṣàdédé yọnu lásìkò tó wà lórí eré, èyí tó fà á tó fi lọ kọlu ọkọ̀ ńlá ti mẹ́sídíìsì náà.
Taofiq ní àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Eko, LASEMA, àjọ́ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ti ìjọba àpapọ̀, FRSC àtàwọn ọlọ́pàá ṣe ìrànwọ́ láti ṣàmójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ní gbogbo àwọn tó farapa níbi ìjàmbá náà ni àwọn ti gbé lọ sílé ìwòsàn ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fún ìtọ́jú tó péye.
Nígbà tó ń bá àwọn ẹbí èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dùn lórí àdánù náà, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ LASTMA, Olalekan Bakare-Oki tẹmpẹlẹmọ ìdí táwọn èèyàn nílò láti máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lójú pópó pàápàá lásìkò pọ̀pọ̀ ṣìnṣìn ọdún yìí.
Bakare-Oki tún rọ pàrọwà sáwọn awakọ̀ láti máa ṣe pẹ̀lẹ́ lójú pópó, kí wọ́n dènà eré àsápajúdé, kí wọ́n sì rí dájú pé ọkọ̀ wọn wà ní pípé kí wọ́n tó máa gbe jáde.















