Bàlúù akérò já, ọ̀pọ̀ kú, èèyàn 25 móríbọ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọpọ eeyan lo ti ku bayii lẹyin ti baluu akero kan ti eeyan mẹtadinlaadọrin wa ninu rẹ ja ni orilẹede Kazakhstan.
Ileeṣẹ iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede naa sọ wi pe eeyan marundinlọgbọn lo moribọ ninu ijamba baluu to ja naa.
Baluu ọhun la gbọ wi pe o jẹ ti ileeṣẹ baluu orilẹede Azerbaijan, o si gbina bi o ṣe n bọ wa silẹ nitosi ilu Aktau. Ko tii si ẹni le sọ ohun gan ni pato to fa baluu to ja naa.
Baluu naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ J2-8243 n gbera lati ilu Baku ti i ṣe olu ilu Azerbaijan lọ si ilu Grozny lorilẹede Russia.
Iroyin sọ pe wọn yi irinajo rẹ pada nitori kurukuru ọjọ to bolẹ nibẹ.
Fidio kan eyi ti ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters fi idi rẹ mulẹ ṣe afihan bi baluu naa ṣe n fi ere tete ja bọ nilẹ.
Iṣẹju aaya lẹyin to balẹ ni ina nla sọ lagbegbe naa.
Arinrinajo mejilelọgọta lo pẹlu awọn oṣiṣẹ inu baluu naa marun un lo wa ninu baluu Embraer 190 naa lasiko to ja, iyẹn gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ileeṣẹ eto irinna lorilẹede naa ṣe sọ.
Ọmọ orilẹede Azabaijan lo pọ ju lara awọn ero inu baluu naa, bakan naa lawọn miran lati orilẹede Russia, Kazakhstan ati Kyrgystan pẹlu wa ninu rẹ.
Awọn alaṣẹ sọ pe iṣẹ nlọ lai si idiwọ o ni papakọ ofurufu ilu Aktau.
BBC ti kan si awọn alaṣẹ ileeṣẹ baluu Azerbaijan Airlines ati Embraer fun ọrọ wọn lori iṣẹlẹ naa.















