Ìfẹ̀hónúhàn bẹ́ sílẹ̀ ní Syria lẹ́yìn tí àwọn kan dáná sun igi ọdún Keresimesi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹhonuhan ti bẹ silẹ ni Syria lẹyin ti awọn eeyan kan dana sun igi ọdun Keresimi.
Iṣẹlẹ naa ti mu ki awọn eeyan ilẹ ọhun ke si ijọba orilẹede naa lati daabo awọn eeyan kereje to jẹ ọmọlẹyin Krisiti nibẹ.
Fidio igi naa ti a foju ri ṣafihan bo ṣe n jo ni gbagede Suqaylabiyah, to jẹ ilu ti awọn ọmọlẹyin Krisiti pọ si.
Ẹgbẹ Hayat Tahrir al-Sham (HTS), to le Aarẹ Bashar al-Assad kuro lori oye ni awọn ti fi ṣikun mu awọn jagujagun kan to wa lati ilẹ okere, ti awọn funra si pe awọn lo dana sun igi naa.
Aṣoju HTS ti ṣleri pe awọn yoo daabo bo ẹtọ awọn ẹlẹsin mii to yatọ si Musulumi lorilẹede naa.
Ẹgbẹgbẹrun awọn oluwọde lo ya bo igboro ti wọn si n fẹhonuhan lati Damascus si Suqaylabiyah lagbegbe Hama.
- Iléẹjọ́ ju Olorí tẹ́lẹ̀, Naomi ati Oriyomi Hamzat sọ́gbá ẹ̀wọ̀n
- Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ láàrín ọdún kan tí Ọba Ghandi Olaoye gba ọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi Soun ìlú Ogbomoso
- Ààrín òrú làwọn ọlọ́pàá ń pè láti wá gba béèlì Abdulkadir lai mọ̀ pé ó ti kú sí àtìmọ́lé wọn - Ẹbí ọ̀dọ́kùnrin tó kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá ní Kwara
Ṣaaju ni aworan awọn jagunjagun meji kan ti wọn wọ iboju ti jade lori ayelujara nibi ti wọn ti n sọ ina si igi Keresimesi ọhun.
Oniruru ẹya ati ẹsin lo wa ni Syria; lara wọn ni awọn eeyan Kurd, Armenia, Assyria, Kristẹni, Druz, Alawite Shia ati awọn ọmọ Arab ti wọn jẹ Sunni.
Ọsẹ meji sẹyin ni ijọba Bashar al-Assad ṣubu si ọwọ awọn ọmọ ogun ọlọtẹ, eyii to fi opin si ijọba mọlẹbi ọkunrin naa to ti wa lori oye lati aadọta ọdun sẹyin.
Amọ ọpọ eeyan lo n woye bi ẹgbẹ ọhun yoo ṣe ṣejọba orilẹede naa bayii.
Amọ ẹgbẹ agbẹsunmọni ṣi ni ẹgbẹ naa gẹgẹ bii ikede ajọ UN, ijọba ilẹ Amẹrika, Yuroopu ati ijọba ilẹ Gẹẹsi.















