Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ láàrín ọdún kan tí Ọba Ghandi Olaoye gba ọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi Soun ìlú Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Soun of Ogbomoso/Instagram
Yoruba bọ wọn ni ati dade kiniun ko ṣẹyin Olodumare, bẹẹ gan an lọrọ ṣe ri pẹlu Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege Kẹta tori ọpọ lo gbagbọ wi pe akọsilẹ lo jẹ fun Ghandi lati jẹ ọba nitori ibi to ti n bọ.
Ọba Ghandi ti jẹ pasitọ fun bii ọgbọn ọdun ni ijọ RCCG, koda, orilẹede Amẹrika lo wa ko to wa jẹ ọba ilu abinibi rẹ, Ogbomoso.
Amọ, gẹgẹ bi Yoruba ṣe maa n sọ, ikoko ti yoo jẹ ẹta idi rẹ yoo pọn.
Lati bii ọdun kan bayii ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti gbe ọpa aṣẹ fun Ọba Ghandi ni o ti n koju oriṣiiriṣii ipenija lori apere awọn baba nla rẹ.
Wọnyi lawọn nnkan to ti ṣẹlẹ laarin ọdun kan ti Ọba Ghandi gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Soun ilu Ogbomoso:
Ile ẹjọ wọgile iyansipo Ọba Ghandi Olaoye gẹgẹ bii Soun tuntun
Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to kalẹ silu Ogbomosos wọgile iyansipo Soun tuntun fun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye.
Ijọba ipinlẹ Oyo lo kede Pasitọ Ghandi Olaoye gẹgẹ bi Soun tuntun ti awọn afọbajẹ ilu naa si fi jẹ ọba lọjọ Kẹjọ osu Kẹsan dun 2023.
Saaju asiko yii ni ọmọ oye miran, ti wọn dijọ n du ipo Soun, Kabir Laoye ti pe ẹjọ pe Ghandi Olaoye ko lẹtọ lati du ipo Soun.
Ile ẹjọ si pasẹ nigba naa pe ijọba ipinlẹ Oyo ko gbọdọ yan ẹnikẹni sipo naa, titi ti oun yoo fi gbe idajọ oun kalẹ.
Amọ ikede jade sita lẹyin naa pe ijọba ipinlẹ Oyo ti yan Pasitọ Ghandi Laoye bii Soun tilẹ Ogbomoso tuntun.
Ki lo de ti adajọ fi wọgile iyansipo Soun tuntun?
Ọmọọba Kabir Olaoye to pe ẹjọ lati tako iyansipo Ghandi salaye pe aise deede wa ninu ilana ti wọn fi yan an.
O wa n rọ ile ẹjọ giga naa lati wọle iyansipo ọba tuntun yii, ko si pasẹ fun awọn afọbajẹ lati bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye miran.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Adedokun to n gbọ ẹjọ naa wa kede pe iyansipo ọba Laoye ko bofinmu.
Bakan naa lo pasẹ pe ki awọn afọbajẹ lọ bẹrẹ ilana ọtun lati yan Soun tuntun
Saaju ni Adajọ Adedokun ti wọgile ẹbẹ mẹta ti ọkan ninu awọn olupẹjọ, Ọmọọba Adeyemi Taofiq Akorede Laoye gbe siwaju rẹ.
Awọn ẹbẹ naa loun naa fi n pe iyansipo oriade tuntun naa nija
Ijọba ipinlẹ Oyo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ to rọ Soun Ogbomoso tuntun loye
Ijọba ipinlẹ Oyo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ to rọ Soun ilu Ogbomosho, Oba Ghandi Afolabi Olaoye, loye.
Yatọ si ẹjọ kọtẹmilọrun yii, ijọba tun bẹbẹ pe ki ile ẹjọ maṣe gba ki wọn yọ ori ade ọhun loye titi ti yoo fi gbọ ẹjọ ti awọn pe.
Olupẹjọ naa tun n bere pe ki awọn to pe ẹjọ akọkọ, eyii ti ile ẹjọ da lare maṣe ṣe ohunkohun lati yọ Ghandi loye lasiko yii.
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni Adajọ K. A. Adedokun da ẹjọ naa laarin ọmọba Muhammed Olaoye ati ijọba ipinlẹ Oyo atawọn mọkanla mii, ninu eyii to ti ni kudiẹkudiẹ wa ninu iyansipo ọba Ghandi Olaoye, nitori naa ko fi ipo naa silẹ.
Lẹyin idajọ ọhun ni Akin Onigbinde, SAN, pe ẹjọ kotẹmilọrun lorukọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn mii ti ọrọ naa kan nipinlẹ lori idajọ to gba ade Ọba lori Soun tuntun.
Ipẹjọ yii ni agbẹjọro ijọba ti fa koko mẹfa yọ ninu eyii to ti tako idajọ ile ẹjọ akọkọ.
O ni awọn ẹri to wa nilẹ tako idajọ to waye pe Ghandi ko yẹ loye Soun ilu Ogomosho.
Lara awọn ti ijọba pe lẹjọ kotẹmilọrun yii ni agbẹjọro Oladapo Atanda, ijọba ibilẹ ariwa Ogbomosho ati igbimọ afọbajẹ Ariwa Ogbomosho.
Awọn to ku ni agbẹjọro S.A. Mohammed, ileeṣẹ Mohammed & Mohammed & Co., Mobolaji Chambers, Kola Fatoye, Oloye Samuel Otolorin, Oloye Salawu Ajadi, Oloye Tijani Abioye, Oloye David Adeniran Ojo, atawọn mii.
Aawọ laarin Soun Ogbomoso ati Imaamu Agba Ayilara

Oríṣun àwòrán, Soun Palace
Wahala aarin Ṣọun Ogbomọṣọ ati Immamu agba Sheikh Ayilara bẹrẹ nigba ti imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun Ogbomọṣọ lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Oun ana lo fi Ayilara jẹ oye Imaamu agba lọdun 2021 ko to waja, eyi ti Imaamu agba naa si n sọ wi pe iyansipo oun ba ilakalẹ gbogbo ilana mu ni ibamu pẹlu ẹsin Islam, ti igbimọ onimimọ nipa ẹsin ni ilu Ogbomọṣọ si fọwọ si i.
Amọṣa ọrọ mii suyọ nigba ti Ọba Afọlabi Ghandi Ọlaoye jẹ gẹgẹ bii Ṣọun tuntun ni ilu Ogbomọṣọ lọdun 2023, to si fariga pẹlu bi Ayilara ṣi ṣe n di ipo mu gẹgẹ bii Imaamu agba ilu naa.
Ẹgbẹ awọn Imaamu Ogbomoso da si ifanfa aarin Imaamu agba ati Soun, ọrọ ba ibomiran yọ
Awuyewuye to n waye laaarin Soun ilu Ogbomoso ati Imaamu agba ilu naa tun ti gba ọna miiran yọ bi igbimọ awọn Alfa ilu naa se ti da si bayii.
Igbimo ẹgbẹ awọn Imaamu ati Alfa ti ilu Ogbomoso ti bu ẹnu atẹ lu ifanfa to n waye laaarin Imam agba ilu ọhun Alhaji Toliat Yusuf Ayilara ati Oba ilu naa, Oba Ghandi Olaoye.
Ẹgbẹ awọn Alfa ati Imaamu Ilu Ogbomoso labẹ isakoso Aarẹ musulumi ilẹ Ogbomoso, AbdulGaniyu Owodunni ninu ifọrọwerọ tí ẹgbẹ naa ṣe pẹlu awọn oniroyin ni gbagede Reacreation Club, lo ti ni, iwa ti Imaamu agba ilu Ogbomoso n hu mu ki aisọkan wa laarin awọn Musulumi ilu Ogbomoso.
Ninu ọrọ apilẹkọ ti Aarẹ musulumi ilu Ogbomoso ka lo ti ran Imam Toliat Yusuf leti wí pe ṣaaju ko to gba lawani gẹgẹ bi Imam agba ilu Ogbomosho ni awọn ẹbi Ayilara ti ń fapa janu wi pe kii ṣe ọmọ ile awọn, nitori naa ipo naa ko tọ si.
Ọba Ghandi Soun Ogbomoso yan Imaamu Agba tuntun fun Aafin

Oríṣun àwòrán, Soun palace
Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege 111, Soun ilẹ Ogbomoso yan Habib Ahmed Adekunle Ayilara gẹgẹ bi Imaamu tuntun fun aafin Soun Ogbomoso.
Ọba Olaoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti o fi sita ni ọjọ Ẹti.
Sheikh Habib Ayilara yii ni ẹbi Ayilara fọwọ si tẹlẹ wi pe ki o jẹ Imaamu Agba ilu Ogbomoso.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi naa ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti ko ni maa dari irun laafin nikan.
Ọpọ musulumi lo wa ni aafin Soun nibi ti wọn ti we lawani fun Imaamu Ayilara ọhun to fi mọ Parakoyi Ogbomoso, Alhaji Sirajudeen Aleem, Sẹnẹtọ Fatai Buhari ti Alhaji Yekinni Woleola ṣoju rẹ atawọn olori ẹsin mii l'Ogbomoso.
Parakoyi ilu Ogbomoso ko ṣai fidi rẹ pe aafin Soun ni Imaamu yii wa fun, o ni Imaamu Agba ilu Ogbomoso, Sheikh Teliat Yunus Olusina Ayilara ṣi wa ni ipo rẹ.
O ni ẹjọ to wa lori ipo rẹ si wa nile ẹjọ lọwọ yii.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi naa ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti ko ni maa dari irun laafin nikan.
Ọba Ghandi ni aafin Soun nilo Imaamu ti yoo maa ṣoju oun ninu gbogbo eto tawọn musulumi ba n ṣe yala niluu Ogbomoso tabi nibi miran.
''Mo gbagbọ ibagbepọ oniruusu ẹsin lo le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilu Ogbomoso.
Mi o si ni kaarẹ nipa gbigbaruku ti iṣọkan ilu Ogbomoso fun anfani gbogbo araalu,'' Ọba Olaoye lo sọ bẹẹ.
Idi ti Soun fi yan Imaamu tuntun fun aafin Ogbomoso
Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Oloye Orumogege III ti yan Habib Ahmed Adekunle gẹgẹ bii Imaamu tuntun fun aafin Soun ti ilẹ Ogbomoso.
Eto yii lo waye lẹyin ti awọn Musulumi ilu naa pejọ lati ṣe akanse eto adura fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹtalelọgọta Ọba ohun.
Nibi ayẹyẹ naa ni Soun ti kede pe Imaamu aafin tuntun naa ni yoo maa ṣoju aafin oun ninu gbogbo ipade to nii ṣe pẹlu awọn Musulumi ilu Ogbomoso ati aafin.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni wahala kan ti kọkọ waye laarin Ṣọun ati Imaamu agba Sheikh Toliat Ayilara.
Asiko naa ni imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Ninu oṣu keje ọdun yii ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ayodele Sonubi pe ipade alafia laarin, kabiyesi ati Sheikh Taliat Ayilara, ẹni ti o jẹ imaamu ilu naa.
Ninu ifọrọwerọ BBC Yoruba pẹlu aṣoju aafin lori igbese yii, oloye agba Samuel Otolorin, to jẹ Aarẹ Ago ti ilẹ Ogbomoso ni Soun ko se aṣiṣe pẹlu yiyan imaamu aafin tuntun.
Aarẹ Ago fun ilu Ogbomoso ni lati igba ti Sheikh Toliat Ayilara ti gbe Ọba Ghandi Afolabi Oloye lọ si ile ẹjọ, ni o ti tẹti ninu awọn ojuṣe rẹ si aafin.
Paapaa julọ, o ni Imaamu agba naa ko wa si aafin mọ lati maa lewaju adura fun Soun ni gbogbo ọjọ Jimoh ṣaaju ki wọn to kirun Jimoh ni mọṣalaṣi apapọ Ogbomoso.
Oloye Aarẹ ago ni "ireti ni pe nigba ti Sheikh Toliat Yusuf ti lọ si ile ẹjọ ati wi pe boya yoo ronu piwada funra ara rẹ yoo mu awọn ẹsun ile ẹjọ kuro.
Lẹyin oṣu mẹfa ni kabiyesi wa wo wi pe o yẹ ki awọn ni imaamu ti yoo maa ṣoju aafin, nitori idi eyi ni wọn fi yan imaamu aafin, ipo naa si yatọ si oye Imamu agba.
Gọngọ sọ l'Ogbomoso nibi ayẹyẹ aṣa Ogbomoso 'cradle carnival'
Igbelarugẹ aṣa gbode nibi ayẹyẹ ajọdun aṣa ilu Ogbomoso ti wọn pe ni Ogbomoso Cradles Carnival to waye fun bi ọsẹ kan niluu Ogbomoso.
Ajọdun yii tun wa jẹ asiko ti Kabiesi Ọba Ghandi pe ọdun kan ti o gba ọpa aṣẹ gẹgẹ Soun ilu Ogbomoso.
Eto naa lo ti bẹẹrẹ lati Ọjọbọ ọjọ kọkandinlogun osu Kejila ọdun yii, pẹlu sise afihan awọn oúnjẹ, egungun, asa ati iṣe ilu Ogbomoso.
Ninu ọrọ ikinni kaabo rẹ, Soun Ọba Ghandi Afolabi Orumogege 111 ṣalaye wi pe eto naa jẹ bi ibẹrẹ idagbasoke fun ilu Ogbomoso.




Kabiyesi rọ awọn ọmọ ilu Ogbomoso lati fi ọwọ sọwọpọ pẹlu oun ki idagbasoke le ba ilu Ogbomoso.
O tun rọ awọn Ọba miran to wa ninu ilu Ogbomoso ati agbegbe rẹ lati fowosowopo pẹlu kí ilu Ogbomoso le rọ gbogbo eniyan lọrun.
Aarẹ Onakakafo ilẹ Yoruba Otunba Gani Adams ni iyalẹnu lọ jẹ fun oun nigbati wọn fi iwe ipeni ranṣẹ soun, nitori wi pe gbogbo eniyan ro wi pe Ọba Ghandi Afolabi Olaoye ko ni fayegba igbelarugẹ asa ati isẹ ilu naa nitori o jẹ pasitọ.
Nigbati o n gbosuba fun Ọba Ghandi, o rọ awọn Ọba ilẹ Yoruba lati mu idagbasoke ba aṣa ati Ise ilẹ Yoruba.
O ṣalaye ise pataki ilu Ogbomoso si ilẹ Yoruba lapapo pẹlu ipa ribibi ti Aarẹ Toyese to jẹ Soun fun ilu Ogbomoso ko nigbati o dojuko ogun awọn Fulani, to si daabo bo ilẹ Yoruba lapapọ.
Ninu ọrọ rẹ, Ogbeni William Adeleye ẹni ti ọ tun jẹ alaga eto ohun ṣalaye wi pe, eto naa yoo mu ki idagbasoke baa ilu Ogbomoso papaa julọ awọn ọdọ ilu.
O tesiwaju wi pe pẹlu eto naa Ogbomoso yoo di ilu ti ilẹ kaarọ ojire yoo feran lati wa papaa julo lẹyin ọdun keresimesi, ti yoo si tun mu igbega ba ẹka to irinajo igbafẹ nipinlẹ Oyo.















