Tinubu rọ ọmọ Nàìjíríà láti gbàdúrà fáwọn olórí wọn bí ààrẹ tí ń káwọn krístẹ́nì kú ọdún Keresimesi

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti pe fun ifẹ ati iṣọkan bi awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe n ṣe ọdun Keresimesi lorilẹede Naijiria ati kaakiri agbaye lonii.

Ninu ọrọ ikini to fi ranṣẹ sawọn onigbagbọ, Tinubu sọ pe ọdun Keresimesi jẹ imuṣẹ asọtẹlẹ.

Aarẹ Naijiria ni ọdun Keresimesi n ṣapejuwe iṣẹgun ifẹ, alaafia ati iṣọkan.

''Ni ọjọ ologo ati ọjọ idunnu yii, mo fi tayọ tayọ ki gbogbo ọmọlẹyin Kristi ku ewu ọdun Keresimesi bi gbogbo agbaye ṣe n ṣe ajọyọ ibi Jesu Kristi gẹgẹ bi iwe mimọ ṣe sọ.

Eleyii n sọ fun wa pe imọlẹ le tan lasiko ti okunkun birimu bo ilẹ eyi ti yoo si mu ireti wa fawọn eniyan.

Eyi ko wa fawọn ọmọlẹyin Kristi nikan, gbogbo ẹsin lo wa fun nitori Ọlọrun wa pẹlu wa lai ṣe ani-ani.''

Naijiria wa lọna ipadabọsipo

Tinubu ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa gbadura fawọn wọn sọ pe orilẹede Naijiria wa loju ọna ipadabọsipo ati ilọsiwaju.

Aarẹ rọ awọn kristẹni lati gbagbọ ninu Naijiria si bi wọn ṣe n yayọ ọdun Keresimesi.

Tinubu ni ''bi a ti n ṣe ọdun Keresimesi, ẹ jẹ ka maa ranti awọn eeyan to n koju ipenija kan tabi omiran lasiko yii.

Awọn eeyan yii le jẹ alabagbe wa tabi ẹbi wa , wọn le jẹ awọn eeyan to wa nibi iṣẹ tabi ile ijọsin wa.

Kii ṣe owo nikan ni eeyan le fi ṣaanu fun ẹlomiran, ọrọ iyanju lasan ni ẹlomiran nilo lasiko yii.

A ko gbọdọ gbagbe awọn ọmogun wa ti wọn fi ẹmi wọn le ilẹ lati maa daabo bo araalu.

Ẹ jẹ ki a maa fi adura ran wọn lọwọ ki a si maa gbaruku ti wọn.

Bakan naa, ẹ jẹ ka gbaruku ti awọn olori wa nitori ajeje ọwọ o gbẹru dori, agbajọ ọwọ ni aa fi ṣọya.

O dami loju wi pe Naijiria wa lọna ipadabọsipo, ọjọ iwaju orilẹede yii si dara.''

Tinubu ko ṣai kẹdun lẹẹkan si pẹlu awọn ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ itẹra-ẹnipa to ṣẹlẹ nibi ti wọn ti n pin ounjẹ ọfẹ ni Ibadan, Abuja ati Anambra.

Aarẹ gbadura wi pe iru iṣẹlẹ bayii ko ni waye mọ lorilẹede Naijiria.